-
Ẹ̀kọ́ Èké Kìíní: Ẹ̀mí Èèyàn Kì Í KúIlé Ìṣọ́—2009 | November 1
-
-
Ẹ̀kọ́ Èké Kìíní: Ẹ̀mí Èèyàn Kì Í Kú
Báwo ni ẹ̀kọ́ èké yìí ṣe bẹ̀rẹ̀? Ìwé The New Encyclopædia Britannica (1988), ìdìpọ̀ 11 sọ lójú ìwé 25 pé, àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí gbà pẹ̀lú àwọn ará Gíríìkì pé ẹ̀mí èèyàn kì í kú, wọ́n sì sọ pé Ọlọ́run ti fi ẹ̀mí yìí sí ara èèyàn láti ìpilẹ̀ṣẹ̀.
Kí ni Bíbélì sọ? ‘Ó pa dà sí erùpẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ náà gan-an, ìrò inú rẹ̀ run.’—Orin Dáfídì 146:4, Bibeli Yoruba Atọ́ka.
Ṣé àwa èèyàn ní “ẹ̀mí” tó máa ń wà láàyè lẹ́yìn tí ara wa bá ti kú? Bíbélì kọ́ni pé Ọlọ́run fi ipá ìwàláàyè tàbí ẹ̀mí sínú èèyàn àti ẹranko, èémí ló sì ń jẹ́ kí ẹ̀mí lè máa ṣiṣẹ́. Ẹ̀mí yìí ló ń gbé ara ró. Àmọ́ tí ara èèyàn tàbí ti ẹranko kò bá mí mọ́, tí kò sì lè mú kí ẹ̀mí tí Ọlọ́run fi sínú rẹ̀ máa ṣiṣẹ́, èyí á yọrí sí ikú. Wọn kò sì ní mọ ohunkóhun mọ́.—Jẹ́nẹ́sísì 3:19; Oníwàásù 3:19-21; 9:5.
Látìgbà tí àwọn èèyàn ti gbà gbọ́ pé ẹ̀mí èèyàn kì í kú ni onírúurú ìbéèrè ti ń jẹ yọ, lára irú ìbéèré yìí ni: Ibo ni ẹ̀mí tó kúrò ní ara èèyàn máa ń lọ lẹ́yìn tí onítọ̀hún bá kú? Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn burúkú lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kú? Nígbà tí àwọn tó ń pera wọn ní Kristẹni gba ẹ̀kọ́ èké yìí gbọ́ pé ẹ̀mí èèyàn kì í kú, èyí mú kí wọ́n gba ẹ̀kọ́ èké míì láyè, ìyẹn sì ni ẹ̀kọ́ nípa iná ọ̀run àpáàdì.
Fi àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí wéra: Oníwàásù 3:19; Mátíù 10:28; Ìṣe 3:23
ÒKODORO ÒTÍTỌ́:
Bí èèyàn bá ti kú, onítọ̀hún ti ṣaláìsí nìyẹn
-
-
Ẹ̀kọ́ Èké Kejì: Àwọn Èèyàn Burúkú Ń Joró Ní Ọ̀run ÀpáàdìIlé Ìṣọ́—2009 | November 1
-
-
Ẹ̀kọ́ Èké Kejì: Àwọn Èèyàn Burúkú Ń Joró Ní Ọ̀run Àpáàdì
Báwo ni ẹ̀kọ́ èké yìí ṣe bẹ̀rẹ̀? “Nínú gbogbo àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì ayé àtijọ́, Plato ni èrò rẹ̀ nípa Ọ̀run Àpáàdì ní ipa tó pọ̀ jù lọ lórí àwọn èèyàn.”—Histoire des enfers (Ìtàn Nípa Ọ̀run Àpáàdì), látọwọ́ Georges Minois, ojú ìwé 50.
“Láti ìdajì ọ̀rúndún kejì Ọdún Olúwa Wa ni àwọn Kristẹni kan tí wọ́n ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nínú ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn Gíríìkì ti bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé ó yẹ kí àwọn lè fi ìmọ̀ ọgbọ́n orí yìí ṣàlàyé ohun tí àwọn gbà gbọ́ . . . Ìmọ̀ ọgbọ́n orí tó rọ̀ wọ́n lọ́rùn jù lọ ni ti Plato [ìyẹn àwọn ẹ̀kọ́ tí Plato fi kọ́ni].”—Ìwé The New Encyclopædia Britannica (1988), Ìdìpọ̀ 25, ojú ìwé 890.
“Ẹ̀kọ́ tí Ṣọ́ọ̀ṣì ń kọ́ àwọn èèyàn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọ̀run àpáàdì wà, ó sì máa wà títí ayérayé. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ọkàn àwọn tó bá kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ tó lè fa ìparun máa ń lọ sí ọ̀run àpáàdì, níbi tí wọ́n á ti máa jìyà nínú ‘iná ayérayé.’ Ìyà tó tóbi jù lọ ní ọ̀run àpáàdì ni bí wọn kò ṣe ní ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́ títí ayérayé.”—Ìwé Catechism of the Catholic Church, ẹ̀dà ti ọdún 1994, ojú ìwé 270.
Kí ni Bíbélì sọ? ‘Nítorí alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n àwọn òkú kò mọ ohun kan, . . . nítorí tí kò sí ète, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀, tàbí ọgbọ́n ní isà-òkú níbi tí ìwọ́ ń rè.”—Oníwàásù 9:5, 10, Bibeli Yoruba Atọ́ka.
Ọ̀rọ̀ Hébérù náà, Sheol, tó túmọ̀ sí “ibi tí àwọn òkú wà,” ni wọ́n tú sí “ọ̀run àpáàdì” nínú àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan. Kí ni ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ti kú? Ṣé wọ́n ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn nínú Ṣìọ́ọ̀lù ni? Rárá o, torí pé wọn “kò mọ ohun kan.” Ìdí nìyẹn tí Jóòbù, tó jẹ́ bàbá ńlá ìgbàanì, fi bẹ Ọlọ́run nígbà tó ń jẹ ìrora àìsàn lílekoko pé: ‘Fi mí pa mọ́ ní isà-òkú [ìyẹn Sheol, lédè Hébérù].’ (Jóòbù 14:13; Bibeli Yoruba Atọ́ka) Kí ni ohun tí Jóòbù béèrè yìí ì bá túmọ̀ sí tí Ṣìọ́ọ̀lù bá jẹ́ ibi ìdálóró ayérayé? Ohun tí ọ̀run àpáàdì wulẹ̀ túmọ̀ sí nínú Bíbélì ni isà-òkú, ìyẹn ibi tí èèyàn kò ti ní lè ṣe ohunkóhun mọ́.
O ò rí i pé ohun tí ọ̀run àpáàdì túmọ̀ sí yìí bọ́gbọ́n mu, ó sì bá Ìwé Mímọ́ pàápàá mu. Ẹ̀ṣẹ̀ búburú wo ni èèyàn lè dá tó máa mú kí Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ dá onítọ̀hún lóró títí ayérayé? (1 Jòhánù 4:8) Àmọ́ ṣá o, tí ẹ̀kọ́ nípa iná ọ̀run àpáàdì bá jẹ́ ẹ̀kọ́ èké, ẹ̀kọ́ pé gbogbo èèyàn rere máa lọ sí ọ̀run wá ń kọ́?
Fi àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí wéra: Sáàmù 146:3, 4; Ìṣe 2:25-27; Róòmù 6:7, 23
ÒKODORO ÒTÍTỌ́:
Ọlọ́run kì í dá èèyàn lóró ní ọ̀run àpáàdì
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]
Barrators—Giampolo/The Doré Illustrations For Dante’s Divine Comedy/Dover Publications Inc.
-
-
Ẹ̀kọ́ Èké Kẹta: Gbogbo Èèyàn Rere Ló Ń Lọ Sí Ọ̀runIlé Ìṣọ́—2009 | November 1
-
-
Ẹ̀kọ́ Èké Kẹta: Gbogbo Èèyàn Rere Ló Ń Lọ Sí Ọ̀run
Báwo ni ẹ̀kọ́ èké yìí ṣe bẹ̀rẹ̀? Lẹ́yìn tí àwọn àpọ́sítélì Jésù kú, ìyẹn ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kejì Sànmánì Kristẹni, àwọn Bàbá Ìjọ ayé ìgbàanì di aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì. Ìwé New Catholic Encyclopedia (2003), Ìdìpọ̀ 6, ojú ìwé 687 ṣàpèjúwe àwọn ẹ̀kọ́ wọn, ó ní: “Ẹ̀kọ́ tó gbòde nígbà náà ni pé ìgbádùn kẹlẹlẹ ló máa wà lọ́run fún àwọn ọkàn tó bá ti fi ara sílẹ̀, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ṣe ìwẹ̀nùmọ́ tó pọn dandan fún wọn lẹ́yìn ikú.”
Kí ni Bíbélì sọ? “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.”—Mátíù 5:5.
Òótọ́ ni pé Jésù ṣèlérí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé òun máa “pèsè ibì kan” sílẹ̀ fún wọn ní ọ̀run, ó jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo olódodo kọ́ ló ń lọ síbẹ̀. (Jòhánù 3:13; 14:2, 3) Ìdí nìyẹn tó fi ní ká máa gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ “gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:9, 10) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ibi méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Ọlọ́run ṣèlérí pé àwọn olódodo máa jogún. Àwọn díẹ̀ máa lọ jọba pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run, èyí tó sì pọ̀ jù nínú wọn ló máa wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 5:10.
Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, ṣọ́ọ̀ṣì ìpilẹ̀ṣẹ̀ yí èrò rẹ̀ pa dà nípa ohun tó yẹ kí àwọn Kristẹni máa ṣe lórí ilẹ̀ ayé. Kí nìyẹn wá yọrí sí? Ìwé The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Kò pẹ́ rárá tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì fi fi ara wọn rọ́pò Ìjọba Ọlọ́run tí àwọn èèyàn ń retí.” Ni ṣọ́ọ̀ṣì bá bẹ̀rẹ̀ sí í fìdí agbára rẹ̀ múlẹ̀ nípa lílọ́wọ́ nínú ìṣèlú, kò sì ka ọ̀rọ̀ Jésù tó ṣe kedere sí pé, kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun má ṣe jẹ́ “apá kan ayé.” (Jòhánù 15:19; 17:14-16; 18:36) Olú Ọba Ilẹ̀ Róòmù, ìyẹn Kọnsitatáìnì mú kí ṣọ́ọ̀ṣì pa àwọn kan tì lára àwọn ohun tó gbà gbọ́, lára àwọn ẹ̀kọ́ náà ni ẹ̀kọ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́.
Fi àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí wéra: Sáàmù 37:10, 11, 29; Jòhánù 17:3; 2 Tímótì 2:11, 12
ÒKODORO ÒTÍTỌ́:
Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn èèyàn rere ló máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé, wọn kò ní lọ sí ọ̀run
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 6]
Art Resource, NY
-
-
Ẹ̀kọ́ Èké Kẹrin: Ọlọ́run Jẹ́ Mẹ́talọ́kanIlé Ìṣọ́—2009 | November 1
-
-
Ẹ̀kọ́ Èké Kẹrin: Ọlọ́run Jẹ́ Mẹ́talọ́kan
Báwo ni ẹ̀kọ́ èké yìí ṣe bẹ̀rẹ̀? “Àwọn kan lè ronú pé ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tó wọnú ìsìn Kristẹni nígbà tí ọ̀rúndún kẹrin ń parí lọ ni ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan. Tá a bá ní ká wò ó lọ́nà kan, òótọ́ ni . . Kí ọ̀rúndún kẹrin tó parí, èrò nípa ‘Ọlọ́run kan nínú Ẹni mẹ́ta’ kò fìdí múlẹ̀ dáadáa, ó sì dájú pé àwọn Kristẹni kò tíì gbà á wọlé sínú ìgbé ayé wọn, kò sì sí lára ìgbàgbọ́ wọn.”—New Catholic Encyclopedia (1967), Ìdìpọ̀ 14, ojú ìwé 299.
“Àpérò kan wáyé nílùú Niséà ní May 20, ọdún 325 [Sànmánì Kristẹni]. Ọba Kọnsitatáìnì fúnra rẹ̀ ló ṣalága tó sì darí ìjíròrò tó wáyé níbẹ̀, òun fúnra rẹ̀ ló sì dábàá . . . ọ̀ràn pàtàkì tó ṣàlàyé bí Kristi ṣe jẹ́ sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ tí wọ́n gbé jáde níbi àpérò náà, pé ‘ọ̀kan náà ní Kristi àti Baba.’ Torí pé ẹ̀rù olú ọba náà ń ba àwọn bíṣọ́ọ̀bù, gbogbo wọn ló buwọ́ lu ìwé pé àwọn tẹ́wọ́ gba ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ náà, àyàfi àwọn méjì kan, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀ràn náà kò tẹ́ ọ̀pọ̀ nínú wọn lọ́rùn.”—Encyclopædia Britannica (1970), Ìdìpọ̀ 6, ojú ìwé 386.
Kí ni Bíbélì sọ? Sítéfánù ‘kún fún ẹ̀mí mímọ́, ó tẹjú mọ́ ọ̀run, ó sì rí ògo Ọlọ́run àti Jésù ń dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. Ó sì wí pé, Wò ó, mo rí ọ̀run ṣí sílẹ̀ àti Ọmọ-ènìyàn ń dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.’—Ìṣe 7:55, 56, Bibeli Mimọ.
Kí ni ìran yìí jẹ́ ká mọ̀? Nígbà tí Sítéfánù kún fún ẹ̀mí mímọ́, ó rí Jésù tó ‘dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.’ Ó ṣe kedere pé kì í ṣe pé Jésù lọ di Ọlọ́run nígbà tó jíǹde tó sì pa dà sí ọ̀run, kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀dá ẹ̀mí kan tó yàtọ̀ sí Ọlọ́run ni. Ìran tí Sítéfánù rí yìí kò sì fi hàn pé ẹnì kan wà nípò kẹta sí Ọlọ́run. Láìka ìsapá tí àwọn kan ń ṣe láti wá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tí wọ́n máa fi ti ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan lẹ́yìn sí, Marie-Émile Boismard, tó jẹ àlùfáà ìjọ Dominic sọ nínú ìwé rẹ̀ tó pe àkọlé rẹ̀ ní À l’aube du christianisme—La naissance des dogmes (Bí Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìsìn Ṣe Bẹ̀rẹ̀ Nígbà Tí Ẹ̀sìn Kristẹni Bẹ̀rẹ̀), ó ní: “Kò sí ibi tá a ti lè rí gbólóhùn náà kà nínú Májẹ̀mú Tuntun pé . . . ẹni mẹ́ta ló wà nínú Ọlọ́run kan.”
Ẹ̀kọ́ ìsìn tí Ọba Kọnsitatáìnì ṣagbátẹrù rẹ̀ yìí ni wọ́n fẹ́ fi fòpin sí àwọn àríyànjiyàn tó ń wáyé láàárín àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ní ọ̀rúndún kẹrin. Àmọ́ dípò ìyẹn, ìbéèrè míì ló gbé dìde, ìbéèrè ọ̀hún ni pé: Ṣé Màríà, ìyẹn obìnrin tó bí Jésù, ni “Ìyá Ọlọ́run”?
Fi àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí wéra: Mátíù 26:39; Jòhánù 14:28; 1 Kọ́ríńtì 15:27, 28; Kólósè 1:15, 16
ÒKODORO ÒTÍTỌ́:
Ìgbà tí ọ̀rúndún kẹrin ń parí lọ ni ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan wọnú ẹ̀sìn Kristẹni
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 7]
Museo Bardini, Florence
-