Sún Mọ́ Ọlọ́run
Rere Tó Wà Lọ́kàn Ẹni Ló Ń Wò
“GBOGBO ọkàn-àyà ni Jèhófà ń wá, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú sì ni ó ń fi òye mọ̀.” (1 Kíróníkà 28:9) Àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí yẹn mú ká mọyì ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí Jèhófà ní sí wa. Láìka àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa sí, ohun rere tó wà lọ́kàn wa ni Jèhófà máa ń wò. A rí èyí kedere nínú ọ̀rọ̀ tó sọ nípa Ábíjà nínú ìwé 1 Àwọn Ọba 14:13.
Inú agbo ilé táwọn ìkà èèyàn wà ní Ábíjà ń gbé. Jèróbóámù bàbá rẹ̀ ni olórí ìjọba apẹ̀yìndà.a Jèhófà pinnu láti pa gbogbo ilé Jèróbóámù run pátápátá, “gan-an gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ènìyàn bá gbá ẹlẹ́bọ́tọ kúrò.” (1 Àwọn Ọba 14:10) Ṣùgbọ́n Ọlọ́run pàṣẹ pé kìkì ẹnì kan ní ilé Jèróbóámù, ìyẹn Ábíjà tó ti ṣàìsàn dójú ikú ní kí wọ́n sin lọ́nà tó gbayì.b Kí nìdí? Ọlọ́run ṣàlàyé pé: “Nítorí ìdí náà pé ohun rere kan sí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni a ti rí nínú rẹ̀ ní ilé Jèróbóámù.” (1 Àwọn Ọba 14:1, 12, 13) Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa Ábíjà?
Bíbélì kò sọ pé Ábíjà jẹ́ olóòótọ́ olùjọ́sìn Ọlọ́run. Síbẹ̀, ohun rere kan wà nínú rẹ̀. Ohun rere náà jẹ́ “sí Jèhófà,” ó ṣeé ṣe kó jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà. Àwọn òǹkọ̀wé tí wọ́n jẹ́ rábì sọ pé, ó ṣeé ṣe kí Ábíjà máa rìnrìn àjò ìsìn lọ sí tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù tàbí pé ó mú àwọn ẹ̀ṣọ́ tí bàbá rẹ̀ fi sí ojú ọ̀nà kúrò, àwọn tí wọn kò jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sí Jerúsálẹ́mù.
Ohun yòówù kí nǹkan rere náà jẹ́, ohun tó gbàfiyèsí ni. Lákọ̀ọ́kọ́, ohun tó jẹ́ ojúlówó ni. Ohun rere náà wà “nínú rẹ̀,” ìyẹn nínú ọkàn rẹ̀. Èkejì ni pé ohun rere náà ṣàrà ọ̀tọ̀. Ábíjà fi ohun rere yìí hàn bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń gbé “ní ilé Jèróbóámù.” Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé: “Ó yẹ ká gbóríyìn gan-an fún àwọn tó ń ṣe rere láìka ti gbígbé tí wọ́n gbé láàárín àwọn èèyàn tàbí ìdílé burúkú sí.” Ọ̀mọ̀wé míì sọ pé nǹkan rere tí Ábíjà ṣe “hàn gbangba . . . , bí àwọn ìràwọ̀ ṣe máa ń tàn lójú sánmà dúdú àti bí ìgbà tí igi kédárì tó lẹ́wà jù lọ bá wà láàárín àwọn igi tó wọ́wé.”
Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé ọ̀rọ̀ tó wà ní 1 Àwọn Ọba 14:13 kọ́ wa ní ohun kan tó dára nípa Jèhófà àti ohun tó ń wò nínú wa. Rántí pé ohun rere kan ló “rí nínú” Ábíjà. Ó hàn pé Jèhófà wo inú ọkàn Ábíjà títí tó fi rí ohun rere kan níbẹ̀. Ọ̀mọ̀wé kan ṣàpèjúwe rẹ̀ pé, tá a bá fi Ábíjà wé àwọn ará ilé rẹ̀, ńṣe ló dà bíi péálì kan ṣoṣo “nínú òkìtì òkúta wẹ́ẹ́wẹ̀ẹ̀wẹ́.” Jèhófà mọyì ohun rere náà, ó sì san èrè nítorí rẹ̀, ó ṣàánú fún Ábíjà nìkan ṣoṣo nínú ìdílé burúkú náà.
Ǹjẹ́ kò mú ọkàn ẹni balẹ̀ láti mọ̀ pé, ohun rere tó wà lọ́kàn wa ni Jèhófà ń wò, ó sì mọyì rẹ̀ láìka kùdìẹ̀-kudiẹ wa sí? (Sáàmù 130:3) Mímọ́ èyí yẹ kó mú wa sún mọ́ Jèhófà, Ọlọ́run tó ń wo inú ọkàn wa láti rí ohun rere tó wà níbẹ̀ ì bá tiẹ̀ ṣe kékeré pàápàá.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Jèróbóámù gbé ìjọsìn ère ọmọ màlúù kalẹ̀ ní apá àríwá ìjọba Ísírẹ́lì ẹlẹ́yà mẹ́wàá láti má ṣe jẹ́ káwọn èèyàn lọ sí Jerúsálẹ́mù láti jọ́sìn Jèhófà ní tẹ́ńpìlì ibẹ̀.
b Ní àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, sísin òkú ẹnì kan lọ́nà tí kò gbayì fi hàn pé Ọlọ́run kò fojúure wo onítọ̀hún.—Jeremáyà 25:32, 33.