Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìgbà wo ni Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà di agbára ayé keje inú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì?
▪ Ère gàgàrà tó jẹ́ ti wúrà, fàdákà, bàbà àti amọ̀ tí Nebukadinésárì Ọba rí kò dúró fún gbogbo àwọn agbára ayé. (Dán. 2:31-45) Àwọn márùn-ún tó ṣàkóso láti ìgbà ayé Dáníẹ́lì tí wọ́n sì ní ipa tó ṣe gúnmọ́ lórí ọ̀ràn àwọn èèyàn Ọlọ́run nìkan ló dúró fún.
Àpèjúwe tí Dáníẹ́lì ṣe nípa ère náà fi hàn pé ńṣe ni Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà máa jáde wá látinú Róòmù, kì í ṣe pé ó máa ṣẹ́gun Róòmù. Dáníẹ́lì rí i pé irin tó wà ní ojúgun ère náà ló dé ibi ẹsẹ̀ àti àwọn ọmọ ìka ẹsẹ̀ rẹ̀. (Irin náà dà pọ̀ mọ́ amọ̀ ní ibi ẹsẹ̀ àti àwọn ọmọ ìka ẹsẹ̀ rẹ̀.)a Èyí fi hàn pé ńṣe ni Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà máa ti inú ojúgun tó jẹ́ irin náà jáde wá. Ìtàn jẹ́rìí sí i pé bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn. Ní apá ìparí ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó jẹ́ apá kan Ilẹ̀ Ọba Róòmù tẹ́lẹ̀ rí bẹ̀rẹ̀ sí í mókè. Nígbà tó yá, Amẹ́ríkà náà di orílẹ̀-èdè tí a kò lè kóyán rẹ̀ kéré. Àmọ́, agbára ayé keje inú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kò tíì fara hàn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kò tíì jọ gbé ohun pàtàkì kankan ṣe títí di ìgbà yẹn, àfi ní ìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní.
Ní àkókò yẹn, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni “àwọn ọmọ ìjọba náà” ti ń fi ìtara wàásù jù lọ, oríléeṣẹ́ wọn sì wà ní ìlú Brooklyn, ní ìpínlẹ̀ New York. (Mát. 13:36-43) Àwọn Kristẹni tó jẹ́ ẹni àmì òróró ń fi ìtara wàásù ní àwọn orílẹ̀-èdè tí Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì ń ṣàkóso lé lórí. Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ti Amẹ́ríkà pawọ́ pọ̀ láti bá àwọn olóṣèlú tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá àwọn méjèèjì jagun. Nítorí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni tó túbọ̀ gbilẹ̀ lákòókò ogun, àwọn ìjọba wọ̀nyí ṣe àtakò sí àwọn tí wọ́n jẹ́ apá kan irú ọmọ “obìnrin” Ọlọ́run, wọ́n fòfin de àwọn ìwé tí wọ́n ń tẹ̀, wọ́n sì ju àwọn tó ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù sẹ́wọ̀n.—Ìṣí. 12:17.
Nítorí náà, ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, ó hàn kedere pé kì í ṣe apá ìparí ọ̀rúndún kẹtàdínlógún tí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í mókè ni agbára ayé keje bọ́ sí ipò ìṣàkóso. Kàkà bẹ́ẹ̀, èyí ṣẹlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Olúwa.b
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Amọ̀ tí ó dà pọ̀ mọ́ irin náà dúró fún àwọn èèyàn tó wà lábẹ́ ìṣàkóso Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà tó le bí irin. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, amọ̀ yìí kò jẹ́ kó rọrùn fún un láti máa lo agbára rẹ̀ tó bí ì bá ṣe fẹ́.
b Àlàyé tí a ṣe níbí yìí la fi ṣe àtúnṣe ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 57, ìpínrọ̀ 24 nínú ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì àti àwọn àtẹ ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 56 àti 139.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Àwọn arákùnrin mẹ́jọ láti oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n ní oṣù June, ọdún 1918 rèé