OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Ṣé lóòótọ́ ni Jésù jí àwọn èèyàn dìde?
Jésù jí Lásárù dìde lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rin tó ti kú
Bíbélì sọ ní ṣàkó pé Jésù jí àwọn òkú dìde. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kì í ṣe àròsọ torí Bíbélì sọ ibi tí wọ́n ti ṣẹlẹ̀ gan-an àti àkókò pàtó tí wọ́n ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 31 Sànmánì Kristẹni, ọ̀pọ̀ èèyàn tẹ̀ lé Jésù láti Kápánáúmù títí dé Náínì. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n bá èrò rẹpẹtẹ tó ń ṣọ̀fọ̀, Jésù sì jí ẹni tó kú náà dìde. Ọkàn wa balẹ̀ pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn torí pé ó wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà tún ṣojú ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn.—Ka Lúùkù 7:11-15.
Jésù tún jí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ dìde lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rin tó ti kú. Òótọ́ ni àjíǹde tó wáyé lọ́jọ́ náà torí pé ọ̀rọ̀ náà ṣojú ọ̀pọ̀ èèyàn.—Ka Jòhánù 11:39-45.
Kí nìdí tí Jésù fi jí àwọn èèyàn dìde?
Àánú ló mú kí Jésù jí àwọn tó ti kú dìde. Bákan náà, Jésù tún fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Bàbá rẹ̀, ìyẹn Ẹlẹ́dàá wa tí fún òun lágbára lórí ikú.—Ka Jòhánù 5:21, 28, 29.
Àwọn àjíǹde yìí fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé gbogbo ìlérí tí Jésù ṣe nípa ọjọ́ ọ̀la máa ṣẹ. Ó máa jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn dìde títí kan àwọn aláìṣòdodo tí kò mọ̀ nípa Ọlọ́run tòótọ́. Àwọn wọ̀nyí máa láǹfààní láti mọ Jèhófà, kí wọ́n sì fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.—Ka Ìṣe 24:15.