-
Kí Ni Ṣìọ́ọ̀lù àti Hédíìsì?Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
-
-
ÀFIKÚN
Kí Ni Ṣìọ́ọ̀lù àti Hédíìsì?
Ó JU àádọ́rin ìgbà lọ tí ọ̀rọ̀ èdè Hébérù náà, sheʼohlʹ àti ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì náà, haiʹdes fara hàn nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ọ̀rọ̀ méjèèjì ló sì jẹ mọ́ ikú. Àwọn olùtumọ̀ Bíbélì kan túmọ̀ wọn sí “sàréè,” “ọ̀run àpáàdì,” tàbí “ihò.” Àmọ́, ní ọ̀pọ̀ èdè, kò sí àwọn ọ̀rọ̀ tó lè gbé ìtumọ̀ tó wà nínú ọ̀rọ̀ Hébérù àti Gíríìkì náà yọ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé “Ṣìọ́ọ̀lù” àti “Hédíìsì” ni Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lò. Kí làwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí túmọ̀ sí gan-an? Jẹ́ ká wo bí wọ́n ṣe lò wọ́n nínú onírúurú ẹsẹ Bíbélì.
Oníwàásù 9:10 sọ pé: “Kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù, ibi tí ìwọ ń lọ.” Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé Ṣìọ́ọ̀lù jẹ́ ibì kan pàtó, tàbí sàréè tí wọ́n sin ẹnì kan sí? Rárá o. Ṣó o rí i, láwọn ibi tí Bíbélì bá ti tọ́ka sí sàréè tàbí ibi ìsìnkú kan pàtó, kì í lo sheʼohlʹ àti haiʹdes, àwọn ọ̀rọ̀ èdè Hébérù àti ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì mìíràn ló máa ń lò. (Jẹ́nẹ́sísì 23:7-9; Mátíù 28:1) Bákan náà, Bíbélì kò lo “Ṣìọ́ọ̀lù” fún ibi ìsìnkú tí wọ́n sin ọ̀pọ̀ èèyàn sí, irú bí ibojì ìdílé tàbí kòtò gìrìwò tí wọ́n sin ọ̀pọ̀ èèyàn pa pọ̀ sí.—Jẹ́nẹ́sísì 49:30, 31.
Kí wá ni “Ṣìọ́ọ̀lù” ń tọ́ka sí gan-an? Bíbélì fi hàn pé ohun tí “Ṣìọ́ọ̀lù” àti “Hédíìsì” ń tọ́ka sí tilẹ̀ ju kòtò gìrìwò tí wọ́n sin ọ̀pọ̀ èèyàn pa pọ̀ sí lọ. Bí àpẹẹrẹ, Aísáyà 5:14 sọ pé Ṣìọ́ọ̀lù jẹ́ “aláyè gbígbòòrò, ó sì ti ṣí ẹnu rẹ̀ sílẹ̀ gbayawu ré kọjá ààlà.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni Ṣìọ́ọ̀lù ti gbé mì, ó dà bíi pé kì í kún, bíi kó sáà máa rí ọ̀pọ̀ èèyàn mì sí i ló ń rí nígbà gbogbo. (Òwe 30:15, 16) Ṣìọ́ọ̀lù kò dà bí ibi ìsìnkú gidi tó jẹ́ pé èèyàn kan tàbí èèyàn díẹ̀ ni wọ́n lè sin síbẹ̀ nítorí pé, ‘Ṣìọ́ọ̀lù kì í ní ìtẹ́lọ́rùn.’ (Òwe 27:20) Ìyẹn ni pé, Ṣìọ́ọ̀lù kì í kún. Nítorí náà, Ṣìọ́ọ̀lù tàbí Hédíìsì kì í ṣe ibi gidi kan téèyàn lè rí níbì kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ipò òkú ni, ìyẹn ibi ìṣàpẹẹrẹ tí ọ̀pọ̀ jù lọ aráyé tí ń sùn nínú oorun ikú wà.
Ẹ̀kọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni nípa àjíǹde tún jẹ́ ká túbọ̀ mọ ìtumọ̀ “Ṣìọ́ọ̀lù” àti “Hédíìsì.” Nígbà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá ń sọ̀rọ̀ nípa Ṣìọ́ọ̀lù àti Hédíìsì, ó máa ń fi hàn pé àwọn tó bá lọ síbẹ̀ yóò jíǹde.a (Jóòbù 14:13; Ìṣe 2:31; Ìṣípayá 20:13) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún fi hàn pé kì í ṣe àwọn tó sin Jèhófà nìkan ló wà ní Ṣìọ́ọ̀lù tàbí Hédíìsì, àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn tí kò sìn ín náà wà níbẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 37:35; Sáàmù 55:15) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”—Ìṣe 24:15.
a Àmọ́, Bíbélì fi hàn pé àwọn òkú tó ‘wà ní Gẹ̀hẹ́nà’ ni kò ní jí dìde, kì í ṣe àwọn òkú tó wà ní Ṣìọ́ọ̀lù tàbí Hédíìsì. (Mátíù 5:30; 10:28; 23:33) Bíi ti Ṣìọ́ọ̀lù àti Hédíìsì, Gẹ̀hẹ́nà náà kì í ṣe ibì kan pàtó, ibi ìṣàpẹẹrẹ ló jẹ́.
-
-
Kí Ni Ọjọ́ Ìdájọ́?Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
-
-
ÀFIKÚN
Kí Ni Ọjọ́ Ìdájọ́?
BÁWO lo ṣe rò pé Ọjọ́ Ìdájọ́ ṣe máa rí? Èrò àwọn kan ni pé, ní Ọjọ́ Ìdájọ́, a óò kó ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn jọ síwájú ìtẹ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run á wá ṣèdájọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn. Wọ́n ní àwọn kan yóò lọ sí ọ̀run rere, àwọn kan yóò sì lọ sínú ìdálóró ayérayé. Àmọ́, ohun tí Bíbélì fi hàn nípa Ọjọ́ Ìdájọ́ yàtọ̀ pátápátá sóhun táwọn èèyàn rò yìí. Bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ṣàpèjúwe Ọjọ́ ìdájọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe àkókò téèyàn á ti máa bẹ̀rù, bí kò ṣe àkókò ìrètí àti ìmúbọ̀sípò.
A rí i bí àpọ́sítélì Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe Ọjọ́ Ìdájọ́ nínú Ìṣípayá 20:11, 12. Ó kà pé: “Mo sì rí ìtẹ́ ńlá funfun kan àti ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀. Ilẹ̀ ayé àti ọ̀run sá lọ kúrò níwájú rẹ̀, a kò sì rí àyè kankan fún wọn. Mo sì rí àwọn òkú, ẹni ńlá àti ẹni kékeré, tí wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ náà, a sì ṣí àwọn àkájọ ìwé sílẹ̀. Ṣùgbọ́n a ṣí àkájọ ìwé mìíràn sílẹ̀; àkájọ ìwé ìyè ni. A sì ṣèdájọ́ àwọn òkú láti inú nǹkan tí a kọ sínú àwọn àkájọ ìwé náà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn.” Ta ni Onídàájọ́ tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ?
Jèhófà ni Onídàájọ́ gíga jù lọ tó máa ṣèdájọ́ aráyé. Àmọ́, ó ti gbé ìdájọ́ náà lé ẹnì kan lọ́wọ́. Nínú Ìṣe 17:31, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Ọlọ́run “ti dá ọjọ́ kan nínú èyí tí ó pète láti ṣèdájọ́ ilẹ̀ ayé tí a ń gbé ní òdodo nípasẹ̀ ọkùnrin kan tí ó ti yàn sípò.” Jésù Kristi tó ti jíǹde ni Onídàájọ́ tí Ọlọ́run yàn yìí. (Jòhánù 5:22) Àmọ́, ìgbà wo ni Ọjọ́ Ìdájọ́ máa bẹ̀rẹ̀? Báwo ló sì ṣe máa gùn tó?
Ìwé Ìṣípayá fi hàn pé Ọjọ́ Ìdájọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá ti pa ètò Sátánì run kúrò lórí ilẹ̀ ayé nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì.a (Ìṣípayá 16:14, 16; 19:19–20:3) Lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì, Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ yóò lọ ṣẹ̀wọ̀n ẹgbẹ̀rún ọdún nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀. Lákòókò náà, àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí wọ́n jẹ́ ajùmọ̀jogún ní ọ̀run yóò máa ṣèdájọ́, wọn yóò sì ṣàkóso “gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú Kristi fún ẹgbẹ̀rún ọdún.” (Ìṣípayá 14:1-3; 20:1-4; Róòmù 8:17) Ọjọ́ Ìdájọ́ kì í ṣe ọjọ́ oníwákàtí mẹ́rìnlélógún tí yóò sáré kọjá lọ. Ẹgbẹ̀rún ọdún ni.
Lákòókò ẹgbẹ̀rúndún náà, Jésù Kristi yóò “ṣèdájọ́ àwọn alààyè àti òkú.” (2 Tímótì 4:1) “Àwọn alààyè” yóò jẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó la ogun Amágẹ́dọ́nì já. (Ìṣípayá 7:9-17) Àpọ́sítélì Jòhánù tún rí “àwọn òkú . . . tí wọ́n dúró níwájú ìtẹ́” ìdájọ́. Jésù ṣèlérí pé “àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Kristi], wọn yóò sì jáde wá” nípasẹ̀ àjíǹde. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Àmọ́, kí ni Ọlọ́run máa wò ṣèdájọ́ gbogbo wọn?
Àpọ́sítélì Jòhánù sọ ìran tó rí, pé: “A sì ṣí àwọn àkájọ ìwé sílẹ̀. . . . A sì ṣèdájọ́ àwọn òkú láti inú nǹkan tí a kọ sínú àwọn àkájọ ìwé náà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn.” Ṣé àwọn ohun táwọn èèyàn ti ṣe tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ló wà nínú àwọn àkájọ ìwé náà ni? Rárá o, nítorí pé kì í ṣe ohun táwọn èèyàn ṣe kí wọ́n tó kú ni Ọlọ́run máa wò ṣèdájọ́. Báwo la ṣe mọ̀? Ohun tí Bíbélì sọ ló jẹ́ ká mọ̀. Ó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ti kú ni a ti dá sílẹ̀ pátápátá kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” (Róòmù 6:7) Ńṣe làwọn òkú á jíǹde láìsí pé Ọlọ́run tún ń ka ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti ṣẹ̀ kí wọ́n tó kú sí wọn lọ́rùn. Nítorí náà, ohun tí àwọn àkájọ ìwé náà gbọ́dọ̀ dúró fún ni àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ àwọn èèyàn lákòókò náà. Káwọn tó la Amágẹ́dọ́nì já àtàwọn tó jíǹde tó lè wà láàyè títí láé, wọ́n gbọ́dọ̀ pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́. Àṣẹ tí wọ́n máa pa mọ́ yìí tún kan àwọn àṣẹ tuntun tó ṣeé ṣe kí Jèhófà ṣí payá lákòókò ẹgbẹ̀rúndún náà. Nípa bẹ́ẹ̀, ohun táwọn èèyàn bá ṣe lákòókò Ọjọ́ Ìdájọ́ ni Ọlọ́run máa wò ṣèdájọ́ wọn.
Ọjọ́ Ìdájọ́ ló máa jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn yóò láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n sì ṣe é. Èyí fi hàn pé ètò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó pabanbarì yóò wáyé lákòókò náà. Dájúdájú, “òdodo ni àwọn olùgbé ilẹ̀ eléso yóò kọ́.” (Aísáyà 26:9) Àmọ́ lákòókò náà, kì í ṣe gbogbo èèyàn ní yóò fẹ́ láti máa ṣe ohun tí Ọlọ́run bá fẹ́. Aísáyà 26:10 sọ pé: “Bí a tilẹ̀ fi ojú rere hàn sí ẹni burúkú, kò kúkú ní kọ́ òdodo. Ní ilẹ̀ ìfòtítọ́-hùwà ni yóò ti máa hùwà lọ́nà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu, kì yóò sì rí ọlá ògo Jèhófà.” Lákòókò Ọjọ́ Ìdájọ́, Ọlọ́run yóò pa àwọn ẹni burúkú bẹ́ẹ̀ run láéláé.—Aísáyà 65:20.
Ní òpin Ọjọ́ Ìdájọ́ náà, àwọn tó bá là á já yóò ti “wá sí ìyè” lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ gẹ́gẹ́ bí èèyàn pípé. (Ìṣípayá 20:5) Nípa bẹ́ẹ̀, àkókò Ọjọ́ Ìdájọ́ ni Ọlọ́run máa mú aráyé bọ̀ sípò ìjẹ́pípé tó dá èèyàn sí níbẹ̀rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 15:24-28) Lẹ́yìn náà ni ìdánwò àṣekágbá yóò wáyé. Ọlọ́run yóò dá Sátánì sílẹ̀ lẹ́wọ̀n yóò sì fún un láyè láti ṣi aráyé lọ́nà lẹ́ẹ̀kan sí i, èyí tó máa jẹ́ àṣemọ rẹ̀. (Ìṣípayá 20:3, 7-10) Ìlérí tí Bíbélì ṣe yóò wá ṣẹ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ sára àwọn tí kò bá jẹ́ kí Sátánì ṣi àwọn lọ́nà. Ìlérí ọ̀hún ni pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29) Dájúdájú, ìbùkún ni Ọjọ́ Ìdájọ́ yóò jẹ́ fún gbogbo èèyàn tó bá jẹ́ onígbọràn!
a Láti lè rí àlàyé nípa ogun Amágẹ́dọ́nì, jọ̀wọ́ wo ìwé Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ Kìíní, ojú ìwé 594 àti 595 àti ojú ìwé 1037 àti 1038. Tún wo orí ogún nínú ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé méjèèjì.
-