Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní December 29, 2014.
Ojú wo la fi ń wo àṣẹ tó wà ní Diutarónómì 14:1 tó ka kíkọ ara ẹni lábẹ léèwọ̀ nígbà téèyàn bá ń ṣọ̀fọ̀ ẹni tó kú? [Nov. 3, w04 9/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 4]
Kí nìdí tá a fi ní kí àwọn ọba Ísírẹ́lì ṣe ẹ̀dà ìwé òfin Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa ‘kà á ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé wọn’? (Diu. 17:18-20) [Nov. 3, w02 6/15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 4]
Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé “ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ túlẹ̀ pa pọ̀,” báwo sì ni àṣẹ yìí nípa fifi àìdọ́gba so pọ̀ ṣe kan àwa Kristẹni? (Diu. 22:10) [Nov. 10, w03 10/15 ojú ìwé 32]
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi ka fífi ipá gba “ọlọ ọlọ́wọ́ tàbí ọmọ orí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò” léèwọ̀? (Diu. 24:6) [Nov. 17, w04 9/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 3]
Ọ̀nà wo ló yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà jẹ́ onígbọràn, kí ló sì yẹ kó máa sún àwa náà ṣiṣẹ́ sin Jèhófà? (Diu. 28:47) [Nov. 24, w10 9/15 ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 4]
Ọ̀nà mẹ́ta gbòógì wo téèyàn lè gbà yan ìyè la rí nínú Diutarónómì 30:19, 20? [Nov. 24, w10 2/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 17]
Ǹjẹ́ ó pọndandan pé ká máa jẹnu wúyẹ́wúyẹ́ nígbà tá a bá ń ka Bíbélì? Ṣàlàyé. (Jóṣ. 1: 8) [Dec. 8, w13 4/15 ojú ìwé 7 ìpínrọ̀ 4]
Ta ni “olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jèhófà” tí Jóṣúà 5:14, 15 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ìṣírí wo sì ni ìtàn yìí fún wa? [Dec. 8, w04 12/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 1]
Kí ló mú kí Ákáánì dẹ́ṣẹ̀, kí sì ni àpẹẹrẹ búburú rẹ̀ kọ́ wa? (Jóṣ. 7:20, 21) [Dec. 15, w10 4/15 ojú ìwé 20 sí 21 ìpínrọ̀ 2 àti 5]
Báwo ni àpẹẹrẹ Kálébù ṣe jẹ́ ìṣírí fún wa lóde òní? (Jóṣ. 14:10-13) [Dec. 29, w04 12/1 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 2]