ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp20 No. 3 ojú ìwé 11
  • Àwọn Tó Ń Ṣègbọràn Sí Ọlọ́run Máa Rí Ọ̀pọ̀ Ìbùkún

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Tó Ń Ṣègbọràn Sí Ọlọ́run Máa Rí Ọ̀pọ̀ Ìbùkún
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2020
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • 1. TÁ A BÁ Ń ṢÈGBỌRÀN SÍ ỌLỌ́RUN A MÁA DI ỌLỌ́GBỌ́N
  • 2. TÁ A BÁ Ń ṢÈGBỌRÀN A MÁA LÁYỌ̀
  • “Èyí Ni Ohun Tí Ìfẹ́ fún Ọlọ́run Túmọ̀ Sí”
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • Ṣé O “Ṣe Tán Láti Ṣègbọràn”?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Kí Ni Jèhófà Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • “Èmi Ha Wà ní Ipò Ọlọ́run Bí?”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2020
wp20 No. 3 ojú ìwé 11
Ìdílé kan wà pa pọ̀, inú wọn ń dùn. Ìyá àti ọmọbìnrin kan ń gbọ́únjẹ. Bàbá àti ọmọbìnrin kejì ń wo fọ́tò ní pálọ̀.

Tá a bá ń ṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run, a máa ní ayọ̀ tòótọ́

Àwọn Tó Ń Ṣègbọràn Sí Ọlọ́run Máa Rí Ọ̀pọ̀ Ìbùkún

Wòlíì Mósè sọ pé tá a bá ń ṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run, a máa rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (Diutarónómì 10:13; 11:27) Kì í ṣe torí kí Ọlọ́run má bàa fìyà jẹ wá la ṣe ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu. Àwọn ohun rere tá a mọ̀ nípa Ọlọ́run ló ń mú ká máa gbọ́ràn sí i lẹ́nu, a sì tún ń ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, a ò sì fẹ́ ṣe ohunkóhun tó lè bà á nínú jẹ́. “Ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run túmọ̀ sí nìyí, pé ká pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.”​—1 Jòhánù 5:3.

Àmọ́, ọ̀nà wo la lè gbà rí ìbùkún Ọlọ́run tá a bá ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu? Jẹ́ ká wo ọ̀nà méjì yìí.

1. TÁ A BÁ Ń ṢÈGBỌRÀN SÍ ỌLỌ́RUN A MÁA DI ỌLỌ́GBỌ́N

“Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, ẹni tó ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, . . . tó ń jẹ́ kí o mọ ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn.”​—ÀÌSÁYÀ 48:17.

Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa mọ̀ wá, ó sì ń pèsè ìtọ́sọ́nà tá a nílò. Tá a bá fẹ́ káwọn ohun tó ń kọ́ wa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó dáa, a gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ látinú Ìwé Mímọ́ ká lè mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe ká sì máa fi àwọn ohun tó ń kọ́ wa ṣèwà hù.

2. TÁ A BÁ Ń ṢÈGBỌRÀN A MÁA LÁYỌ̀

“Aláyọ̀ ni àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”​—LÚÙKÙ 11:28.

Lónìí, àìmọye àwọn èèyàn ló ní ayọ̀ gidi torí wọ́n ń ṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan wà nílùú Sípéènì tó máa ń bínú fùfù tó sì máa ń kanra mọ́ àwọn èèyàn, títí kan ìyàwó rẹ̀. Lọ́jọ́ kan, ó ka ìwé wòlíì Mósè nípa bí Jósẹ́fù ọmọ Jékọ́bù ṣe jẹ́ oníwà tútù. Wọ́n ta Jósẹ́fù bí ẹrú, wọ́n sì sọ ọ́ sẹ́wọ̀n láì jẹ̀bi; síbẹ̀ ó jẹ́ oníwà tútù àti èèyàn àlàáfíà, ó sì dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ ẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì, orí 37-45) Ọkùnrin ará Sípéènì náà sọ pé: “Bí mo ṣe ń ronú nípa àpẹẹrẹ Jósẹ́fù mú kí n ní ìwà tútù, inúure àti ìkóra-ẹni-níjàánu. Ní báyìí, ọkàn mi balẹ̀ mo sì ń láyọ̀.”

Ìwé Mímọ́ kọ́ wa ní ọ̀pọ̀ nǹkan nípa bó ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn èèyàn. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, wàá rí oríṣiríṣi ọ̀nà tó o lè gbà ṣe é.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́