ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp20 No. 3 ojú ìwé 12
  • Bí A Ṣe Lè Fìfẹ́ Hàn Sí Ọmọnìkejì Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí A Ṣe Lè Fìfẹ́ Hàn Sí Ọmọnìkejì Wa
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2020
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • OHUN TÍ ÌWÉ MÍMỌ́ SỌ NÍPA ÌFẸ́
  • OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ LÁTI NÍFẸ̀Ẹ́ ỌMỌNÌKEJÌ WA
  • ‘Ẹ Máa Rìn Nínú Ìfẹ́’
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • Ìfẹ́ (Agape)—Ohun Tí Kò jẹ́ Àti Ohun Tí Ó Jẹ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìfẹ́—Ànímọ́ Kan Tó Ṣe Pàtàkì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Bá A Ṣe Lè Mú Kí Ìfẹ́ Tá A Ní Sáwọn Ará Túbọ̀ Lágbára
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2020
wp20 No. 3 ojú ìwé 12
Aláàánú ará Samáríà tó wà nínú àkàwé Jésù ń bu òróró sójú ọgbẹ́ ọkùnrin tí wọ́n lù tí wọ́n sì pa tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà.

Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn lóòótọ́, àá máa ṣoore fún wọn bí ò tiẹ̀ rọrùn fún wa

Bí A Ṣe Lè Fìfẹ́ Hàn sí Ọmọnìkejì Wa

Nítorí pé àtọmọdọ́mọ Ádámù èèyàn àkọ́kọ́ ni wá, ìdílé kan ni gbogbo wa. Ńṣe ló yẹ kí gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn, àmọ́ ó ṣòro gan-an láti rí irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ lóde òní. Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa.

OHUN TÍ ÌWÉ MÍMỌ́ SỌ NÍPA ÌFẸ́

‘Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.’​—LÉFÍTÍKÙ 19:18.

“Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín.”​—MÁTÍÙ 5:44.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ LÁTI NÍFẸ̀Ẹ́ ỌMỌNÌKEJÌ WA

Wo ohun tí Ọlọ́run sọ nípa ìfẹ́ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní 1 Kọ́ríńtì 13:​4-7:

“Ìfẹ́ máa ń ní sùúrù àti inú rere.”

Rò ó wò ná: Báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ táwọn èèyàn bá ń mú sùúrù fún ẹ, tí wọ́n ń finúure hàn sí ẹ, tí wọn ò sì bínú sí ẹ tó o bá ṣàṣìṣe?

“Ìfẹ́ kì í jowú.”

Rò ó wò ná: Báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ táwọn èèyàn bá ń fura sí ẹ gan-an tàbí tí wọ́n ń jowú ẹ?

Ìfẹ́ “kì í wá ire tirẹ̀ nìkan.”

Rò ó wò ná: Báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ táwọn èèyàn bá ń fara mọ́ èrò rẹ tí wọn ò sì rin kinkin mọ́ èrò tiwọn?

Ìfẹ́ “kì í di èèyàn sínú.”

Rò ó wò ná: Tí àwa èèyàn bá ṣẹ Ọlọ́run, tá a sì ronú pìwà dà, Ọlọ́run ṣe tán láti dárí jì wá. “Kì í fìgbà gbogbo wá àṣìṣe, kì í sì í bínú títí lọ.” (Sáàmù 103:9) A máa ń mọrírì rẹ̀ gan-an tẹ́ni tá a ṣẹ̀ bá dárí jì wá. Torí náà, ó yẹ ká múra tán láti dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ wá.​—Sáàmù 86:5.

Ìfẹ́ “kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo.”

Rò ó wò ná: Nígbà tí ohun tó burú bá ṣẹlẹ̀ sí wa, a kì í fẹ́ káwọn èèyàn máa yọ̀ nítorí ìyà tó ń jẹ wá. Torí náà, kò yẹ káwa náà máa yọ̀ nígbà táwọn èèyàn bá ń jìyà, ì báà jẹ́ àwọn tó ti ṣàìdáa sí wa tẹ́lẹ̀.

Ká tó lè rí ìbùkún Ọlọ́run gbà, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn láwọn ọ̀nà tá a ti sọ yìí láìka ẹni tí wọ́n jẹ́ sí. Ọ̀nà tó dáa tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́