ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w22 December ojú ìwé 28-30
  • Ṣé O Ti Múra Tán Láti “Jogún Ayé”?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé O Ti Múra Tán Láti “Jogún Ayé”?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • MÚRA TÁN LÁTI SỌ AYÉ DI PÁRÁDÍSÈ
  • MÚRA TÁN LÁTI BÓJÚ TÓ ÀWỌN TÓ BÁ JÍǸDE
  • MÚRA TÁN LÁTI KỌ́ ÀWỌN TÓ BÁ JÍǸDE LẸ́KỌ̀Ọ́
  • Àjíǹde Máa Wà!
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Àwọn Wo Ni A Óò Jí Dìde? Ibo Ni Wọn Yóò Máa Gbé?
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Apa 10
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run
  • Kí Ni Àjíǹde?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
w22 December ojú ìwé 28-30
Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ kí wọ́n lè sọ ayé di Párádísè. Àwọn kan ń kó ìdọ̀tí, àwọn kan ń kọ́lé, àwọn yòókù sì ń tún ọgbà ṣe.

Ṣé O Ti Múra Tán Láti “Jogún Ayé”?

GBOGBO wa là ń retí ìgbà tí ìlérí Jésù máa ṣẹ, ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn oníwà tútù, torí wọ́n máa jogún ayé.” (Mát. 5:5) Àwọn ẹni àmì òróró máa jogún ayé torí wọ́n máa bá Jésù jọba lọ́run. (Ìfi. 5:10; 20:6) Lónìí, ọ̀pọ̀ lára àwa Kristẹni tòótọ́ là ń retí láti jogún ayé, àá sì máa gbe inú ẹ̀ títí láé, àá di ẹni pípé, àá sì máa gbé lálàáfíà àti ayọ̀. Àmọ́ kí àwọn nǹkan yìí tó ṣẹlẹ̀, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ la máa ṣe. Mẹ́ta lára àwọn iṣẹ́ náà rèé: A máa sọ ayé di Párádísè, a máa bójú tó àwọn tó jíǹde, a sì máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, máa ronú nípa àwọn nǹkan tó o lè ṣe báyìí táá fi hàn pé ó wù ẹ́ láti ṣe lára àwọn iṣẹ́ náà.

MÚRA TÁN LÁTI SỌ AYÉ DI PÁRÁDÍSÈ

Nígbà tí Jèhófà sọ fáwa èèyàn níbẹ̀rẹ̀ pé, “kí ẹ kún ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀,” ohun tó ń sọ ni pé a máa sọ gbogbo ayé di Párádísè. (Jẹ́n. 1:28) Àwọn tó máa jogún ayé ló máa ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ yẹn. Torí pé ọgbà Édẹ́nì ò sí mọ́, àwa la ṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ ayé di Párádísè. Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ la máa ṣe torí pé lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì, gbogbo ibi tó ti bà jẹ́ láyé la máa tún ṣe. Ó dájú pé iṣẹ́ ńlá ló máa jẹ́!

Èyí rán wa létí iṣẹ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe nígbà tí wọ́n pa dà dé láti Bábílónì. Odindi àádọ́rin (70) ọdún ni kò fi séèyàn kankan tó gbé lórí ilẹ̀ wọn. Àmọ́ Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé Jèhófà máa ràn wọ́n lọ́wọ́, wọ́n á sì sọ ilẹ̀ náà di ibi tó lẹ́wà. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé: “Ó máa mú kí aginjù rẹ̀ rí bí Édẹ́nì, ó sì máa mú kí aṣálẹ̀ rẹ̀ tó tẹ́jú rí bí ọgbà Jèhófà.” (Àìsá. 51:3) Jèhófà sì jẹ́ kí wọ́n ṣàṣeyọrí. Bákan náà, Jèhófà máa ran àwọn tó máa jogún ayé lọ́wọ́ láti sọ ayé di Párádísè. Kódà ní báyìí, o lè máa ṣe àwọn nǹkan táá fi hàn pé ó wù ẹ́ láti ṣe lára iṣẹ́ náà lọ́jọ́ iwájú.

Àwọn nǹkan tó o lè ṣe ni pé kó o máa tún ilé ẹ àti àyíká ẹ ṣe, kó lè mọ́ tónítóní. Ohun tó yẹ kó o máa ṣe nìyẹn táwọn tẹ́ ẹ jọ ń gbé ládùúgbò ò bá tiẹ̀ ṣe ìmọ́tótó. O tún lè lọ ṣèrànwọ́ nígbà tí wọ́n bá ń ṣàtúnṣe Ilé Ìpàdé àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ wa. Tó bá sì ṣeé ṣe, o lè yọ̀ǹda ara ẹ láti ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá lágbègbè rẹ. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé o fẹ́ ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ẹ lọ́wọ́ tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro. Bi ara ẹ pé, ‘Ṣé mo lè kọ́ iṣẹ́ tí mo lè lò láti fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ tí mo bá láǹfààní láti jogún ayé?’

Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan ń tún Ilé Ìjọsìn wa ṣe.

MÚRA TÁN LÁTI BÓJÚ TÓ ÀWỌN TÓ BÁ JÍǸDE

Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí Jésù jí ọmọbìnrin Jáírù dìde, ó sọ pé kí wọ́n fún ọmọ náà ní ohun tó máa jẹ. (Máàkù 5:42, 43) Ó lè má ṣòro láti bójú tó ohun tí ọmọ ọdún méjìlá (12) yẹn nílò. Àmọ́ ronú nípa iṣẹ́ ńlá tá a máa ṣe láti bójú tó àwọn tó bá jíǹde nígbà tí Jésù bá mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ pé, ‘gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí máa gbọ́ ohùn rẹ̀, wọ́n á sì jáde wá.’ (Jòh. 5:28, 29) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó máa ṣẹlẹ̀, tá a bá wò ó dáadáa, àá rí i pé àwọn tó jíǹde máa nílò oúnjẹ, ibùgbé àti aṣọ. Ṣé ohun tó ò ń ṣe báyìí fi hàn pé o ti múra tán láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nígbà yẹn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á dáa kó o bi ara ẹ láwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí.

Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe báyìí táá fi hàn pé o múra tán láti jogún ayé?

Inú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yìí ń dùn bí wọ́n ṣe ń kí àwọn ará tó wá láti orílẹ̀-èdè míì káàbọ̀ sí àpéjọ àgbáyé tí wọ́n ṣe ní Paris.

Tí wọ́n bá ṣèfilọ̀ níjọ yín pé alábòójútó àyíká fẹ́ bẹ̀ yín wò, ṣé o máa ń pè é wá sílé ẹ kẹ́ ẹ lè jọ jẹun? Tí iṣẹ́ ẹni tó ti ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì bá yí pa dà tí wọ́n sì ní kó wá máa sìn níjọ yín tàbí tí iṣẹ́ alábòójútó àyíká kan bá dópin, ṣé o lè bá wọn wá ibi tí wọ́n á máa gbé? Tí wọ́n bá fẹ́ ṣe àpéjọ agbègbè tàbí àkànṣe àpéjọ lágbègbè ẹ, ṣé o lè lọ ṣiṣẹ́ níbẹ̀ ṣáájú àti lẹ́yìn àpéjọ náà tàbí kó o yọ̀ǹda ara ẹ láti lọ kí àwọn àlejò tó wá láti orílẹ̀-èdè míì káàbọ̀?

MÚRA TÁN LÁTI KỌ́ ÀWỌN TÓ BÁ JÍǸDE LẸ́KỌ̀Ọ́

Ohun tó wà nínú Ìṣe 24:15 jẹ́ ká mọ̀ pé àìmọye èèyàn ni Jèhófà máa jí dìde. Ọ̀pọ̀ lára wọn ò láǹfààní láti mọ Jèhófà kí wọ́n tó kú, àmọ́ wọ́n máa láǹfààní yẹn tí wọ́n bá jíǹde.a Àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n nírìírí ló máa kọ́ àwọn tó bá jíǹde lẹ́kọ̀ọ́. (Àìsá. 11:9) Arábìnrin Charlotte tó ti wàásù ní Yúróòpù, South America àti Áfíríkà náà ń retí ìgbà tó máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Ó fayọ̀ sọ pé: “Mò ń retí ìgbà tí mo máa kọ́ àwọn tó bá jíǹde lẹ́kọ̀ọ́. Tí mo bá kà nípa ẹni tó ti gbé ayé rí nígbà àtijọ́, mo sábà máa ń sọ pé: ‘Ká ní ẹni yìí mọ Jèhófà ni, ìgbésí ayé ẹ̀ ì bá dáa jù báyìí lọ.’ Ara mi ti wà lọ́nà láti kọ́ àwọn tó máa jíǹde lẹ́kọ̀ọ́.”

Kódà àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tó gbé ayé kí Jésù tó wá sáyé náà máa kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jèhófà. Wo ayọ̀ tó o máa ní tó o bá láǹfààní láti ṣàlàyé fún Dáníẹ́lì bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó kọ ṣe ṣẹ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò yé e nígbà yẹn. (Dán. 12:8) Tún wo bó ṣe máa rí lára ẹ tó o bá ń ṣàlàyé fún Rúùtù àti Náómì pé ìdílé wọn ni Mèsáyà ti wá. Ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó tá a bá kópa nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó máa kárí ayé nígbà tí kò ní sí wàhálà tó kúnnú ayé lónìí mọ́!

Arábìnrin kan ń fún obìnrin kan ní ìwé níbi tí wọ́n ti ń fọṣọ.

Àwọn nǹkan wo lo lè máa ṣe báyìí táá fi hàn pé ó wù ẹ́ láti kọ́ àwọn tó bá jíǹde lẹ́kọ̀ọ́? Ohun tó o lè ṣe ni pé kó o mú kí ọ̀nà tó ò ń gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ dáa sí i, kó o sì máa wàásù déédéé. (Mát. 24:14) Kódà tí ọjọ́ orí ẹ tàbí àwọn nǹkan míì ò bá jẹ́ kó o lè ṣe tó bó o ṣe fẹ́, tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ìyẹn á fi hàn pé ó ń wu ìwọ náà láti kọ́ àwọn tó bá jíǹde lẹ́kọ̀ọ́.

Ìbéèrè pàtàkì tó yẹ kó o bi ara ẹ ni pé, ṣé lóòótọ́ ló ń wù ẹ́ láti jogún ayé? Ṣé ò ń retí láti sọ ayé di Párádísè, kó o bójú tó àwọn tó bá jíǹde, kó o sì tún kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́? Ó yẹ kó o fi hàn pé o múra tán láti ṣe bẹ́ẹ̀, kó o máa yọ̀ǹda ara ẹ báyìí láti ṣe àwọn iṣẹ́ tó jọ èyí tó o máa ṣe nígbà tó o bá jogún ayé!

a Wo àpilẹ̀kọ náà, ‘Wọ́n Ń Sọ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Di Olódodo’ nínú Ilé Ìṣọ́ September 2022.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́