Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìgbà wo ni iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe báyìí máa dópin?
Jésù sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.” (Mát. 24:14) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “òpin” nínú ẹsẹ yìí, ẹsẹ 6 àti ẹsẹ 13 ni teʹlos. Òpin ti ẹsẹ yìí ń sọ ni ìgbà táyé tí Sátánì ń darí yìí máa dópin ní Amágẹ́dọ́nì. (Ìfi. 16:14, 16) Torí náà, àá máa wàásù ìhìn rere náà títí á fi kù díẹ̀ kí Amágẹ́dọ́nì bẹ̀rẹ̀. Òye tuntun tá a ní nìyí.
Òye tá a ní tẹ́lẹ̀ ni pé iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere máa parí nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀, ìyẹn nígbà tí Bábílónì Ńlá bá pa run. (Ìfi. 17:3, 5, 15, 16) A rò pé tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀, “ọdún ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà” ti dópin nìyẹn, kò sì ní ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti gbọ́ ìhìn rere mọ́. (Àìsá. 61:2) Bákan náà, a rò pé àwọn tí ò ní pa run nígbà ìpọ́njú ńlá gbọ́dọ̀ ti máa sin Jèhófà kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀. A fi wọ́n wé àwọn Júù tí ò kú nígbà tí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 Ṣ.S.K. A ti sàmì sáwọn èèyàn náà pé wọn ò ní pa run torí pé wọ́n ti ń sin Jèhófà tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ti kórìíra ìwà burúkú. (Ìsík. 5:11; 9:4) Àfiwé yìí yàtọ̀ sóhun tí Jésù ń sọ ní Mátíù 24:14, ó sọ níbẹ̀ pé àwọn èèyàn máa láǹfààní láti gbọ́ ìhìn rere kí òpin tó dé nígbà Amágẹ́dọ́nì.
Òye tuntun tá a ní nípa Mátíù 24:14 tún jẹ́ ká ṣàtúnṣe òye tá a ní nípa Ìfihàn 16:21 tó sọ nípa ìkéde tó dà bí òkúta yìnyín. Ìwádìí tá a ṣe fi hàn pé àwọn ẹsẹ Bíbélì méjì yìí ń ṣàlàyé ara wọn ni. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ohun tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni ohun tí Bíbélì sọ nípa báwọn èèyàn á ṣe tẹ́wọ́ gba ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ìhìn rere náà jẹ́ “òórùn dídùn ti ìyè” fún “àwọn tó ń rí ìgbàlà.” Àmọ́, ó jẹ́ “òórùn ikú” fáwọn ọ̀tá Ọlọ́run. (2 Kọ́r. 2:15, 16) Ìdí táwọn ọ̀tá fi kórìíra ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni pé ìhìn rere náà ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Èṣù ló ń darí ayé burúkú yìí àti pé ayé yìí máa pa run láìpẹ́.—Jòh. 7:7; 1 Jòh. 2:17; 5:19.
Ẹ tún kíyè sí i pé òkúta yìnyín náà máa “pọ̀ lọ́nà tó kàmàmà.” Èyí fi hàn pé ìhìn rere tá a máa wàásù nígbà ìpọ́njú ńlá máa lágbára sí i, ìyẹn ni pé a máa kéde orúkọ Jèhófà ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. (Ìsík. 39:7) Lẹ́yìn tí Bábílónì Ńlá bá pa run, ṣé a ṣì máa ráwọn tó máa tẹ́wọ́ gba ìhìn rere yẹn bí òórùn dídùn? Ó ṣeé ṣe kó rí bẹ́ẹ̀. Wọ́n lè rántí pé ọ̀pọ̀ ọdún làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wàásù pé ẹ̀sìn èké máa pa run.
Ẹ jẹ́ ká fi nǹkan tá a sọ yìí wé nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní Íjíbítì àtijọ́ lẹ́yìn tí Ìyọnu Mẹ́wàá ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Lẹ́yìn tí Jèhófà “dá gbogbo ọlọ́run Íjíbítì lẹ́jọ́,” “oríṣiríṣi èèyàn tó pọ̀ rẹpẹtẹ” ló dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Ẹ́kís. 12:12, 37, 38) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé lẹ́yìn táwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì rí i pé Ìyọnu Mẹ́wàá tí Mósè sọ ti ṣẹlẹ̀ ni wọ́n pinnu láti sin Jèhófà.
Àwọn tó bá wá sin Jèhófà lẹ́yìn tí Bábílónì Ńlá pa run máa láǹfààní láti ṣohun tó dáa sáwọn arákùnrin Kristi tó ṣì máa wà láyé nígbà yẹn. (Mát. 25:34-36, 40) Àmọ́ tó bá kù díẹ̀ kí ogun Amágẹ́dọ́nì bẹ̀rẹ̀, àwọn ẹni àmì òróró tó ṣẹ́ kù máa gba èrè wọn lọ́run. Nígbà yẹn, àwọn èèyàn ò ní láǹfààní láti wá sin Jèhófà mọ́, wọn ò sì ní sí lára àwọn àgùntàn.
Òye tuntun tá a ní yìí jẹ́ ká túbọ̀ rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, aláàánú sì ni. Ó dájú pé “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.”—2 Pét. 3:9