ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb17 ojú ìwé 169-170
  • Àwọn Tó Ń Sọ Èdè Kurdish Gba Ẹ̀kọ́ Òtítọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Tó Ń Sọ Èdè Kurdish Gba Ẹ̀kọ́ Òtítọ́
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2017
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2017
yb17 ojú ìwé 169-170
Arábìnrin kan ń fi èdè Kurdish kọ́ obìnrin kan lẹ́kọ̀ọ́

JỌ́JÍÀ

Àwọn Tó Ń Sọ Èdè Kurdish Gba Ẹ̀kọ́ Òtítọ́

GULIZAR sọ pé, “Mi ò lè ṣe kí n máà dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà bó ṣe jẹ́ kí n mọ òun lédè àbínibí mi.”

Ọdún mẹ́jọ ni Gulizar fi dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ ìgbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé tí wọ́n ń ṣe lédè ìbílẹ̀ rẹ̀, ìyẹn èdè Kurdish, ló tó ṣèrìbọmi. Ó wà lára ọ̀pọ̀ àwọn ará Kurd tó gba ẹ̀kọ́ òtítọ́ ní Jọ́jíà lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Àmọ́ àwọn wo là ń pè ní Kurd?

Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ni àwọn tó ń sọ èdè Kurdish ti ń gbé ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrun. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé àtọmọdọ́mọ àwọn ará Mídíà ayé àtijọ́ tí Bíbélì sọ ni wọ́n. (2 Ọba 18:11; Ìṣe 2:9) Ọ̀kan lára èdè àwọn ará Ìráànì ni wọ́n ń sọ.

Lónìí, oríṣiriṣi orílẹ̀-èdè ni ọ̀pọ̀ mílíọ́nù àwọn ará Kurd ń gbé, títí kan Àméníà, Ìráànì, Ìráàkì, Síríà àti Tọ́kì. Nǹkan bí ọ̀kẹ́ kan [20,000] àwọn ará Kurd ló wà ní Jọ́jíà. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, wọ́n sì ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fọ́rọ̀ Ọlọ́run.

Ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] akéde ló ń sọ èdè Kurdish ní Jọ́jíà báyìí, ìjọ mẹ́ta ni wọ́n sì ti ń sọ èdè náà. Lọ́dún 2014, inú gbogbo èèyàn ló ń dùn nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe àpéjọ àgbègbè léde Kurdish nílùú Tbilisi, àwọn èèyàn sì wá láti orílẹ̀-èdè Àméníà, Jámánì, Tọ́kì àti Ukraine.

Àwọn ọmọ àwọn ará Kurd ń gbádùn fídíò Kọ́lá àti Tósìn
    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́