-
Jẹ́nẹ́sísì 41:22-24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 “Lẹ́yìn ìyẹn, mo lá àlá pé ṣírí ọkà méje tó yọmọ dáadáa, tó sì dára+ jáde láti ara pòròpórò kan. 23 Lẹ́yìn náà, ṣírí ọkà méje tó ti rọ, tó tín-ín-rín, tí atẹ́gùn ìlà oòrùn sì ti jó gbẹ hù jáde. 24 Àwọn ṣírí ọkà tín-ín-rín náà wá ń gbé ṣírí ọkà méje tó dára mì. Mo ti rọ́ àlá yìí fún àwọn àlùfáà onídán,+ àmọ́ kò sẹ́ni tó lè sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún mi.”+
-