13 Ni wọ́n bá sọ pé: “Ọkùnrin méjìlá (12) ni àwa ìránṣẹ́ rẹ.+ Ọmọ bàbá kan+ náà ni wá, ilẹ̀ Kénáánì sì ni bàbá+ wa wà. Àbúrò wa tó kéré jù wà lọ́dọ̀ bàbá wa, àmọ́ àbúrò wa kejì ò sí mọ́.”+
7 Wọ́n fèsì pé: “Ọkùnrin náà bi wá nípa ara wa àti àwọn mọ̀lẹ́bí wa pé, ‘Ṣé bàbá yín ṣì wà láàyè? Ṣé ẹ ní arákùnrin míì?’ A sì sọ òótọ́ fún un.+ Báwo la ṣe fẹ́ mọ̀ pé yóò sọ pé, ‘Ẹ mú àbúrò yín wá’?”+