34 Ni Jékọ́bù bá fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sán aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ìbàdí, ó sì ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. 35 Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń gbìyànjú láti tù ú nínú, àmọ́ kò gbà, ó ń sọ pé: “Màá ṣọ̀fọ̀ ọmọ mi wọnú Isà Òkú!”+ Bàbá rẹ̀ sì ń sunkún torí rẹ̀.