19 Ọlọ́run fèsì pé: “Ó dájú pé Sérà ìyàwó rẹ máa bí ọmọkùnrin kan fún ọ, kí o sì sọ ọ́ ní Ísákì.*+ Màá sì fìdí májẹ̀mú mi tí mo bá a dá múlẹ̀, ó máa jẹ́ májẹ̀mú ayérayé fún àtọmọdọ́mọ* rẹ̀.+
17 ó dájú pé màá bù kún ọ, ó sì dájú pé màá mú kí ọmọ* rẹ pọ̀ bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti iyanrìn etí òkun,+ ọmọ* rẹ yóò sì gba ẹnubodè* àwọn ọ̀tá+ rẹ̀ lọ́wọ́ wọn.