8 “Ó tún fún Ábúráhámù ní májẹ̀mú ìdádọ̀dọ́,*+ ó sì bí Ísákì,+ ó dádọ̀dọ́ rẹ̀* ní ọjọ́ kẹjọ,+ Ísákì sì bí* Jékọ́bù, Jékọ́bù sì bí àwọn olórí ìdílé* méjìlá (12).
11 Ó gba àmì kan,+ ìyẹn, ìdádọ̀dọ́,* gẹ́gẹ́ bí èdìdì* òdodo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ tó ní nígbà tó ṣì jẹ́ aláìdádọ̀dọ́,* kí ó lè jẹ́ baba gbogbo àwọn tó ní ìgbàgbọ́+ nígbà tí wọ́n ṣì jẹ́ aláìdádọ̀dọ́, kí a lè kà wọ́n sí olódodo;