20 Lẹ́yìn èyí, wọ́n ròyìn fún Ábúráhámù pé: “Mílíkà náà ti bí àwọn ọmọ fún Náhórì arákùnrin+ rẹ: 21 Úsì ni àkọ́bí rẹ̀, Búsì ni àbúrò àti Kémúélì bàbá Árámù, 22 Késédì, Hásò, Pílídáṣì, Jídíláfù àti Bẹ́túẹ́lì.”+ 23 Bẹ́túẹ́lì bí Rèbékà.+ Àwọn mẹ́jọ yìí ni Mílíkà bí fún Náhórì arákùnrin Ábúráhámù.