-
Jẹ́nẹ́sísì 26:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Máa gbé ilẹ̀+ yìí bí àjèjì, màá wà pẹ̀lú rẹ, màá sì bù kún ọ torí pé ìwọ àti ọmọ* rẹ ni màá fún ní gbogbo ilẹ̀+ yìí, màá sì ṣe ohun tí mo búra fún Ábúráhámù+ bàbá rẹ pé: 4 ‘Màá mú kí ọmọ* rẹ pọ̀ bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run,+ màá sì fún ọmọ* rẹ ní gbogbo ilẹ̀+ yìí; gbogbo orílẹ̀-èdè ayé yóò sì gba ìbùkún fún ara wọn+ nípasẹ̀ ọmọ* rẹ,’
-
-
Ìṣe 7:4, 5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Lẹ́yìn náà, ó jáde kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà, ó sì ń gbé ní Háránì. Lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀ kú,+ Ọlọ́run darí rẹ̀ láti ibẹ̀ pé kí ó lọ máa gbé ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gbé báyìí.+ 5 Síbẹ̀, kò fún un ní ogún kankan nínú rẹ̀, rárá, kò tiẹ̀ fún un ní ibi tó lè gbẹ́sẹ̀ lé; àmọ́ ó ṣèlérí pé òun máa fún un láti fi ṣe ohun ìní, lẹ́yìn rẹ̀ òun á fún ọmọ* rẹ̀,+ bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò tíì ní ọmọ kankan.
-