13 Ó wá sọ fún Ábúrámù pé: “Mọ̀ dájú pé àwọn ọmọ* rẹ máa di àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiwọn, àwọn èèyàn ibẹ̀ á fi wọ́n ṣe ẹrú, wọ́n á sì fìyà jẹ wọ́n fún ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọdún.+
17Nígbà tí Ábúrámù pé ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99), Jèhófà fara han Ábúrámù, ó sì sọ fún un pé: “Èmi ni Ọlọ́run Olódùmarè. Máa bá mi rìn,* kí o sì fi hàn pé o jẹ́ aláìlẹ́bi.*
8 Màá fún ìwọ àti ọmọ* rẹ ní ilẹ̀ tí o gbé nígbà tí o jẹ́ àjèjì,+ ìyẹn gbogbo ilẹ̀ Kénáánì, yóò jẹ́ ohun ìní wọn títí láé, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run+ wọn.”
9 Ìgbàgbọ́ mú kó máa gbé bí àjèjì ní ilẹ̀ ìlérí, bíi pé ó jẹ́ ilẹ̀ àjèjì,+ ó ń gbé inú àgọ́ + pẹ̀lú Ísákì àti Jékọ́bù, àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ajogún ìlérí kan náà.+