ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 31:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Níkẹyìn, Jèhófà sọ fún Jékọ́bù pé: “Pa dà sí ilẹ̀ àwọn bàbá rẹ àti sọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí+ rẹ, mi ò sì ní fi ọ́ sílẹ̀.”

  • Nọ́ńbà 23:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Ọlọ́run kì í ṣe èèyàn lásánlàsàn tó máa ń parọ́,+

      Tàbí ọmọ èèyàn tó máa ń yí èrò pa dà.*+

      Tó bá sọ ohun kan, ṣé kò ní ṣe é?

      Tó bá sì sọ̀rọ̀, ǹjẹ́ kò ní mú un ṣẹ?+

  • Jóṣúà 23:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 “Ẹ wò ó! Mi ò ní pẹ́ kú,* ẹ sì mọ̀ dáadáa pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara* yín pé kò sí ìkankan nínú gbogbo ìlérí tó dáa tí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe fún yín tí kò ṣẹ. Gbogbo wọn ló ṣẹ fún yín. Ìkankan nínú wọn ò kùnà.+

  • Hébérù 6:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 kó lè jẹ́ pé nípasẹ̀ àwọn nǹkan méjì tí kò lè yí pa dà, tí Ọlọ́run ò ti lè parọ́,+ àwa tí a ti sá sí ibi ààbò máa lè rí ìṣírí tó lágbára gbà láti di ìrètí tó wà níwájú wa mú ṣinṣin.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́