-
Jẹ́nẹ́sísì 32:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Mo ti ní àwọn akọ màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin,+ mo sì ń ránṣẹ́ yìí sí olúwa mi láti fi èyí tó o létí, kí n lè rí ojúure rẹ.”’”
-
-
Jẹ́nẹ́sísì 36:6, 7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Lẹ́yìn náà, Ísọ̀ kó àwọn ìyàwó rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, gbogbo àwọn* tó wà ní agbo ilé rẹ̀, agbo ẹran rẹ̀ àti gbogbo àwọn ẹran rẹ̀ yòókù, pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ tó ti ní+ nílẹ̀ Kénáánì, ó sì lọ sí ilẹ̀ míì, níbi tó jìnnà sí Jékọ́bù àbúrò+ rẹ̀. 7 Torí ohun ìní wọn ti pọ̀ débi pé wọn ò lè máa gbé pa pọ̀, ilẹ̀ tí wọ́n ń gbé* ò sì lè tó wọn mọ́ torí agbo ẹran wọn.
-