59 Torí náà, wọ́n jẹ́ kí Rèbékà+ arábìnrin wọn àti olùtọ́jú+ rẹ̀ tẹ̀ lé ìránṣẹ́ Ábúráhámù àti àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ wá. 60 Wọ́n súre fún Rèbékà, wọ́n sì sọ fún un pé: “Arábìnrin wa, wàá di ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún, àtọmọdọ́mọ rẹ yóò sì gba ẹnubodè àwọn tó kórìíra wọn lọ́wọ́ wọn.”+