-
Jẹ́nẹ́sísì 49:5-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 “Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò+ ni Síméónì àti Léfì. Ohun èlò ìwà ipá ni ohun ìjà wọn.+ 6 Má ṣe wá sáàárín wọn, ìwọ ọkàn* mi. Má ṣe bá wọn pé jọ, ìwọ ọlá* mi. Torí wọ́n fi ìbínú pa àwọn ọkùnrin,+ wọ́n sì tún já iṣan ẹsẹ̀* àwọn akọ màlúù láti tẹ́ ara wọn lọ́rùn. 7 Ègún sì ni fún ìbínú wọn, torí ìkà ni wọ́n fi ṣe àti ìrunú wọn, torí ó le jù.+ Jẹ́ kí n tú wọn ká sí ilẹ̀ Jékọ́bù, kí n sì tú wọn ká sáàárín Ísírẹ́lì.+
-