-
Ẹ́kísódù 25:17-20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 “Kí o fi ògidì wúrà ṣe ìbòrí, kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì ààbọ̀, kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀.+ 18 Kí o fi wúrà ṣe kérúbù méjì; kó jẹ́ iṣẹ́ ọnà tí o fi òòlù ṣe sí ìkángun méjèèjì ìbòrí náà.+ 19 Kí o ṣe àwọn kérúbù náà sí ìkángun méjèèjì, kérúbù kan ní ìkángun kọ̀ọ̀kan ìbòrí náà. 20 Kí àwọn kérúbù náà na ìyẹ́ wọn méjèèjì sókè, kí wọ́n fi bo ìbòrí náà,+ kí wọ́n sì dojú kọra. Kí àwọn kérúbù náà sì máa wo ìbòrí náà.
-