-
Ẹ́kísódù 37:6-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Ó fi ògidì wúrà ṣe ìbòrí.+ Gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀.+ 7 Ó wá fi wúra ṣe kérúbù+ méjì sí ìkángun méjèèjì ìbòrí náà, ó jẹ́ iṣẹ́ ọnà tó fi òòlù ṣe.+ 8 Kérúbù kan wà ní ìkángun kan, kérúbù kejì sì wà ní ìkángun kejì. Ó ṣe àwọn kérúbù náà sí ìkángun méjèèjì ìbòrí náà. 9 Àwọn kérúbù méjèèjì na ìyẹ́ wọn sókè, ìyẹ́ wọn sì bo ìbòrí náà.+ Wọ́n dojú kọra, wọ́n sì ń wo ìbòrí náà.+
-