-
Ẹ́kísódù 30:1-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 “Kí o ṣe pẹpẹ kan láti máa fi sun tùràrí;+ igi bọn-ọ̀n-ní ni kí o fi ṣe é.+ 2 Kó ní igun mẹ́rin tó dọ́gba, ìgbọ̀nwọ́* kan ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, kí gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì. Kí pẹpẹ náà àti àwọn ìwo rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan.+ 3 Kí o fi ògidì wúrà bò ó lókè pẹ̀lú ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ yí ká àti àwọn ìwo rẹ̀; kí o sì ṣe ìgbátí wúrà sí i* yí ká. 4 Kí o fi wúrà ṣe òrùka méjì sí ìsàlẹ̀ ìgbátí rẹ̀* ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì tó wà lódìkejì ara wọn, ìyẹn ló máa gba àwọn ọ̀pá tí wọ́n á fi gbé e dúró. 5 Igi bọn-ọ̀n-ní ni kí o fi ṣe àwọn ọ̀pá náà, kí o sì fi wúrà bò wọ́n.
-