-
Ẹ́kísódù 37:25-28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Ó wá fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe pẹpẹ tùràrí.+ Ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dọ́gba, gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì. Pẹpẹ náà àti àwọn ìwo rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan.+ 26 Ó fi ògidì wúrà bò ó lókè pẹ̀lú ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ yí ká àti àwọn ìwo rẹ̀, ó sì ṣe ìgbátí wúrà sí i* yí ká. 27 Ó fi wúrà ṣe òrùka méjì sí ìsàlẹ̀ ìgbátí rẹ̀,* ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì tó wà lódìkejì ara wọn láti gba àwọn ọ̀pá tí wọ́n á fi máa gbé e dúró. 28 Lẹ́yìn náà, ó fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn ọ̀pá, ó sì fi wúrà bò wọ́n.
-