3 wò ó! ọwọ́ Jèhófà+ máa kọ lu àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ nínú oko. Àjàkálẹ̀ àrùn tó le gan-an+ yóò run àwọn ẹṣin, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ràkúnmí, ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran.
11Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Ó ku ìyọnu kan tí màá mú wá sórí Fáráò àti Íjíbítì. Lẹ́yìn náà, ó máa jẹ́ kí ẹ kúrò níbí.+ Ṣe ló máa lé yín kúrò níbí nígbà tó bá gbà pé kí ẹ máa lọ.+
29 Nígbà tó di ọ̀gànjọ́ òru, Jèhófà pa gbogbo àkọ́bí nílẹ̀ Íjíbítì,+ látorí àkọ́bí Fáráò tó wà lórí ìtẹ́ dórí àkọ́bí ẹni tó wà lẹ́wọ̀n* àti gbogbo àkọ́bí ẹranko.+
31 Ló bá pe Mósè àti Áárónì+ ní òru, ó sì sọ pé: “Ẹ gbéra, ẹ kúrò láàárín àwọn èèyàn mi, ẹ̀yin àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù. Ẹ lọ sin Jèhófà bí ẹ ṣe sọ.+