-
Ẹ́kísódù 10:8-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Wọ́n wá mú Mósè àti Áárónì pa dà wá sọ́dọ̀ Fáráò, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ, kí ẹ lọ sin Jèhófà Ọlọ́run yín. Àmọ́ àwọn wo gan-an ló ń lọ?” 9 Ni Mósè bá sọ pé: “Tọmọdé tàgbà wa ló máa lọ, pẹ̀lú àwọn ọmọ wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin, àwọn àgùntàn wa àti àwọn màlúù wa,+ torí a máa ṣe àjọyọ̀ fún Jèhófà.”+ 10 Ó sọ fún wọn pé: “Tí mo bá jẹ́ kí ẹ̀yin àtàwọn ọmọ yín lọ, á jẹ́ pé Jèhófà wà pẹ̀lú yín lóòótọ́!+ Ó ṣe kedere pé nǹkan burúkú kan wà lọ́kàn yín tí ẹ fẹ́ ṣe. 11 Mi ò gbà! Àwọn ọkúnrin yín nìkan ni kó lọ sin Jèhófà, torí ohun tí ẹ béèrè nìyẹn.” Ni wọ́n bá lé wọn kúrò níwájú Fáráò.
-