31 Ló bá pe Mósè àti Áárónì+ ní òru, ó sì sọ pé: “Ẹ gbéra, ẹ kúrò láàárín àwọn èèyàn mi, ẹ̀yin àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù. Ẹ lọ sin Jèhófà bí ẹ ṣe sọ.+ 32 Kí ẹ kó àwọn agbo ẹran yín àti ọ̀wọ́ ẹran yín, kí ẹ sì lọ bí ẹ ṣe sọ.+ Àmọ́ kí ẹ súre fún mi.”