-
Ẹ́kísódù 8:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Àmọ́ àwọn àlùfáà onídán fi agbára òkùnkùn wọn ṣe ohun kan náà, àwọn náà mú kí àkèré jáde sórí ilẹ̀ Íjíbítì.+
-
-
Ẹ́kísódù 8:18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Àwọn àlùfáà onídán náà gbìyànjú láti ṣe ohun kan náà, wọ́n fẹ́ fi agbára òkùnkùn wọn mú kòkòrò jáde,+ àmọ́ wọn ò rí i ṣe. Àwọn kòkòrò náà bo èèyàn àti ẹranko.
-
-
Ẹ́kísódù 9:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Àwọn àlùfáà onídán kò lè dúró níwájú Mósè torí eéwo náà, torí eéwo ti bo àwọn àlùfáà náà àti gbogbo ará Íjíbítì.+
-
-
2 Tímótì 3:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Bí Jánésì àti Jáńbérì ṣe ta ko Mósè, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn yìí ṣe ń ta ko òtítọ́ ṣáá. Ìrònú irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ti dìbàjẹ́, ìgbàgbọ́ wọn ò sì ní ìtẹ́wọ́gbà.
-