ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 7:11, 12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Ni Fáráò bá ránṣẹ́ pe àwọn amòye àti àwọn oníṣẹ́ oṣó. Àwọn àlùfáà onídán ní Íjíbítì+ pẹ̀lú sì fi agbára* wọn ṣe ohun kan náà.+ 12 Kálukú wọn ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, àwọn ọ̀pá náà sì di ejò ńlá; àmọ́ ọ̀pá Áárónì gbé àwọn ọ̀pá wọn mì.

  • Ẹ́kísódù 7:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Lójú ẹsẹ̀, Mósè àti Áárónì ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ gẹ́lẹ́. Ó na ọ̀pá náà sókè, ó sì fi lu omi odò Náílì níṣojú Fáráò àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, gbogbo omi odò náà sì di ẹ̀jẹ̀.+

  • Ẹ́kísódù 7:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Síbẹ̀, àwọn àlùfáà onídán ní Íjíbítì fi agbára òkùnkùn wọn ṣe ohun kan náà,+ ìyẹn sì mú kí ọkàn Fáráò túbọ̀ le, kò sì fetí sí wọn bí Jèhófà ṣe sọ.+

  • Ẹ́kísódù 8:17, 18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Áárónì na ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ jáde, ó sì fi lu erùpẹ̀, àwọn kòkòrò náà wá bo èèyàn àti ẹranko. Gbogbo erùpẹ̀ di kòkòrò abìyẹ́ tó ń mùjẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.+ 18 Àwọn àlùfáà onídán náà gbìyànjú láti ṣe ohun kan náà, wọ́n fẹ́ fi agbára òkùnkùn wọn mú kòkòrò jáde,+ àmọ́ wọn ò rí i ṣe. Àwọn kòkòrò náà bo èèyàn àti ẹranko.

  • Ẹ́kísódù 9:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Àwọn àlùfáà onídán kò lè dúró níwájú Mósè torí eéwo náà, torí eéwo ti bo àwọn àlùfáà náà àti gbogbo ará Íjíbítì.+

  • 2 Tímótì 3:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Bí Jánésì àti Jáńbérì ṣe ta ko Mósè, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn yìí ṣe ń ta ko òtítọ́ ṣáá. Ìrònú irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ti dìbàjẹ́, ìgbàgbọ́ wọn ò sì ní ìtẹ́wọ́gbà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́