-
Ẹ́kísódù 8:31, 32Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
31 Jèhófà ṣe ohun tí Mósè sọ, àwọn eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ náà sì kúrò lọ́dọ̀ Fáráò, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn èèyàn rẹ̀ láìku ẹyọ kan. 32 Àmọ́ Fáráò tún mú kí ọkàn rẹ̀ le, kò sì jẹ́ kí àwọn èèyàn náà lọ.
-
-
Ẹ́kísódù 14:17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Ní tèmi, màá jẹ́ kí ọkàn àwọn ará Íjíbítì le, kí wọ́n lè lépa wọn wọnú òkun, kí n sì ṣe ara mi lógo nípasẹ̀ Fáráò àti gbogbo ọmọ ogun rẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti àwọn agẹṣin rẹ̀.+
-