-
Jẹ́nẹ́sísì 50:24, 25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Níkẹyìn, Jósẹ́fù sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Mi ò ní pẹ́ kú, àmọ́ ó dájú pé Ọlọ́run ò ní gbàgbé yín,+ ó sì dájú pé yóò mú yín kúrò ní ilẹ̀ yìí lọ sí ilẹ̀ tó búra nípa rẹ̀ fún Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù.”+ 25 Jósẹ́fù wá mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì búra, ó ní: “Ó dájú pé Ọlọ́run ò ní gbàgbé yín. Kí ẹ kó egungun mi kúrò níbí.”+
-