-
Ẹ́kísódù 24:17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Lójú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ògo Jèhófà rí bí iná tó ń jẹ nǹkan run lórí òkè náà.
-
-
2 Kíróníkà 7:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Gbàrà tí Sólómọ́nì parí àdúrà rẹ̀,+ iná bọ́ láti ọ̀run,+ ó jó ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ náà, ògo Jèhófà sì kún ilé náà.+ 2 Àwọn àlùfáà kò lè wọnú ilé Jèhófà nítorí pé ògo Jèhófà ti kún ilé Jèhófà.+ 3 Gbogbo àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ń wò nígbà tí iná bọ́ sílẹ̀, tí ògo Jèhófà sì bo ilé náà, wọ́n tẹrí ba, wọ́n sì dojú bolẹ̀ lórí ibi tí a fi òkúta tẹ́, wọ́n wólẹ̀, wọ́n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, “nítorí ó jẹ́ ẹni rere; ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì wà títí láé.”
-