24 iná sì bọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í jó ẹbọ sísun àti àwọn ọ̀rá tó wà lórí pẹpẹ. Nígbà tí gbogbo àwọn èèyàn náà rí i, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe, wọ́n sì dojú bolẹ̀.+
26 Dáfídì mọ pẹpẹ kan+ síbẹ̀ fún Jèhófà, ó sì rú àwọn ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀, ó ké pe Jèhófà, ẹni tó wá fi iná dá a lóhùn+ láti ọ̀run sórí pẹpẹ ẹbọ sísun náà.