-
Diutarónómì 5:7-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 O ò gbọ́dọ̀ ní ọlọ́run kankan yàtọ̀ sí mi.*+
8 “‘O ò gbọ́dọ̀ gbẹ́ ère kankan fún ara rẹ+ tàbí kí o ṣe ohun* kan tó dà bí ohunkóhun lókè ọ̀run tàbí ní ayé tàbí nínú omi nísàlẹ̀. 9 O ò gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún wọn tàbí kí o jẹ́ kí wọ́n sún ọ láti sìn wọ́n,+ torí èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ kí o máa sin òun nìkan ṣoṣo,+ tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá jẹ àwọn ọmọ, dórí ìran kẹta àti ìran kẹrin àwọn tó kórìíra mi,+ 10 àmọ́ tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀* hàn sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ mi títí dé ẹgbẹ̀rún ìran wọn, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́.
-