26“‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí fún ara yín,+ ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe ère gbígbẹ́+ tàbí ọwọ̀n òrìṣà fún ara yín, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ gbé ère òkúta+ tí ẹ gbẹ́ sí ilẹ̀ yín láti forí balẹ̀ fún un;+ torí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.
15 “Torí náà, ẹ ṣọ́ra gidigidi,* torí pé ẹ ò rí ẹnikẹ́ni lọ́jọ́ tí Jèhófà bá yín sọ̀rọ̀ ní Hórébù láti àárín iná náà, 16 kí ẹ má bàa hùwàkiwà nípa gbígbẹ́ ère èyíkéyìí tó jọ ohunkóhun fún ara yín, ohun tó rí bí akọ tàbí abo,+
23 Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má bàa gbàgbé májẹ̀mú tí Jèhófà Ọlọ́run yín bá yín dá,+ ẹ má sì gbẹ́ ère fún ara yín, ohun tó rí bí ohunkóhun tí Jèhófà Ọlọ́run yín kà léèwọ̀ fún yín.+
15 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá gbẹ́ ère+ tàbí tó ṣe ère onírin,*+ tó jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà,+ iṣẹ́ ọwọ́ oníṣẹ́ ọnà,* tó sì gbé e pa mọ́.’ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’*)
29 “Nítorí náà, bí a ṣe jẹ́ ọmọ* Ọlọ́run,+ kò yẹ kí a rò pé Olú Ọ̀run rí bíi wúrà tàbí fàdákà tàbí òkúta, bí ohun tí a fi ọgbọ́n àti iṣẹ́ ọnà èèyàn gbẹ́ lére.+