18 “Kí o yan àwọn onídàájọ́+ àti àwọn olórí fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní gbogbo ìlú* tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ, kí wọ́n sì máa fi òdodo ṣèdájọ́ àwọn èèyàn náà.
25“Tí àwọn èèyàn bá ń bára wọn fa ọ̀rọ̀, kí wọ́n kó ara wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn adájọ́,+ wọ́n á sì bá wọn dá ẹjọ́ wọn, wọ́n á dá olódodo láre, wọ́n á sì dá ẹni burúkú lẹ́bi.+