-
Léfítíkù 6:2-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 “Tí ẹnì* kan bá ṣẹ̀, tó hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà+ torí pé ó tan ọmọnìkejì rẹ̀ jẹ nípa ohun kan tó fi sí ìkáwọ́ rẹ̀ tàbí ohun kan tó fi pa mọ́ sọ́wọ́ rẹ̀+ tàbí tó ja ọmọnìkejì rẹ̀ lólè tàbí tó lù ú ní jìbìtì, 3 tàbí tó rí ohun tó sọ nù, tó sì sẹ́ pé òun ò rí i, tó wá búra èké lórí èyíkéyìí nínú ẹ̀ṣẹ̀ tó dá,+ ohun tó máa ṣe nìyí: 4 Tó bá ti ṣẹ̀, tó sì jẹ̀bi, kó dá ohun tó jí pa dà àti ohun tó fipá gbà, ohun tó fi jìbìtì gbà, ohun tí wọ́n fi sí ìkáwọ́ rẹ̀ tàbí ohun tó sọ nù tí ó rí, 5 tàbí ohunkóhun tó búra èké lé lórí, kó sì san gbogbo rẹ̀ pa dà,+ kó tún fi ìdá márùn-ún rẹ̀ kún un. Kó fún ẹni tó ni ín lọ́jọ́ tí wọ́n bá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó jẹ̀bi.
-