-
Léfítíkù 25:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Ọdún mẹ́fà ni kí ẹ fi fún irúgbìn sí oko yín, ọdún mẹ́fà ni kí ẹ fi rẹ́wọ́ ọgbà àjàrà yín, kí ẹ sì kórè èso ilẹ̀ náà.+ 4 Àmọ́ kí ọdún keje jẹ́ sábáàtì fún ilẹ̀ náà, tí ẹ ò ní ṣiṣẹ́ kankan níbẹ̀, sábáàtì fún Jèhófà. Ẹ ò gbọ́dọ̀ fún irúgbìn sí oko yín tàbí kí ẹ rẹ́wọ́ àjàrà yín.
-