-
Ẹ́kísódù 23:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 “Ọdún mẹ́fà ni kí o fi fún irúgbìn sí ilẹ̀ rẹ, kí o sì fi kórè èso rẹ̀.+ 11 Àmọ́ ní ọdún keje, kí o fi ilẹ̀ náà sílẹ̀ láìro, má fi dá oko. Àwọn tó jẹ́ aláìní nínú àwọn èèyàn rẹ yóò jẹ nínú rẹ̀, àwọn ẹran inú igbó yóò sì jẹ ohun tí wọ́n bá ṣẹ́ kù. Ohun tí o máa ṣe sí ọgbà àjàrà rẹ àti àwọn igi ólífì rẹ nìyẹn.
-