-
Ẹ́kísódù 5:3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Àmọ́ wọ́n sọ pé: “Ọlọ́run àwa Hébérù ti bá wa sọ̀rọ̀. Jọ̀ọ́, a fẹ́ rin ìrìn àjò ọjọ́ mẹ́ta lọ sí aginjù, ká sì rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run wa;+ àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, yóò fi àìsàn kọ lù wá tàbí kó fi idà pa wá.”
-
-
Ẹ́kísódù 10:25, 26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Àmọ́ Mósè sọ pé: “Ìwọ náà máa fún wa ní* ohun tí a máa fi rúbọ àti èyí tí a máa fi rú ẹbọ sísun, a ó sì fi rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run wa.+ 26 Àwọn ẹran ọ̀sìn wa náà máa bá wa lọ. A ò ní jẹ́ kí ẹran* kankan ṣẹ́ kù, torí a máa lò lára wọn láti jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run wa, a ò sì mọ ohun tí a máa fi rúbọ sí Jèhófà àfi tí a bá débẹ̀.”
-