ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 24:5, 6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 “Kí o mú ìyẹ̀fun tó kúnná, kí o fi ṣe búrẹ́dì méjìlá (12) tó rí bí òrùka. Ìyẹ̀fun tó jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà* ni kí o fi ṣe búrẹ́dì kọ̀ọ̀kan. 6 Kí o tò wọ́n ní ìpele méjì, mẹ́fà ní ìpele kan,+ lórí tábìlì tí wọ́n fi ògidì wúrà ṣe, èyí tó wà níwájú Jèhófà.+

  • 1 Sámúẹ́lì 21:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Àlùfáà náà bá fún un ní búrẹ́dì mímọ́,+ torí pé kò sí búrẹ́dì míì nílẹ̀ àfi búrẹ́dì àfihàn, tí a mú kúrò níwájú Jèhófà kí a lè fi búrẹ́dì tuntun rọ́pò rẹ̀ ní ọjọ́ tí a mú un kúrò.

  • 1 Kíróníkà 9:32
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 32 Àwọn kan lára àwọn arákùnrin àwọn ọmọ Kóhátì ló ń bójú tó búrẹ́dì onípele,*+ láti ṣe é sílẹ̀ ní sábáàtì+ kọ̀ọ̀kan.

  • 2 Kíróníkà 13:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Wọ́n ń mú àwọn ẹbọ sísun rú èéfín sí Jèhófà ní àràárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́-ìrọ̀lẹ́+ pẹ̀lú tùràrí onílọ́fínńdà,+ àwọn búrẹ́dì onípele*+ sì wà lórí tábìlì ògidì wúrà, wọ́n máa ń tan ọ̀pá fìtílà wúrà+ àti àwọn fìtílà rẹ̀ ní alaalẹ́,+ nítorí pé à ń ṣe ojúṣe wa fún Jèhófà Ọlọ́run wa; àmọ́ ẹ̀yin ti fi í sílẹ̀.

  • Mátíù 12:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Bó ṣe wọ ilé Ọlọ́run, tí wọ́n sì jẹ àwọn búrẹ́dì tí wọ́n ń gbé síwájú,*+ èyí tí kò bófin mu fún òun àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ láti jẹ, àfi àwọn àlùfáà nìkan?+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́