-
Máàkù 2:25, 26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ ò tíì ka ohun tí Dáfídì ṣe rí ni, nígbà tó ṣaláìní, tí ebi sì ń pa òun àti àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀?+ 26 Nínú ìtàn Ábíátárì+ olórí àlùfáà, bó ṣe wọ ilé Ọlọ́run, tó sì jẹ àwọn búrẹ́dì tí wọ́n ń gbé síwájú,* èyí tí kò bófin mu fún ẹnikẹ́ni láti jẹ àfi àwọn àlùfáà,+ tó sì tún fún àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ jẹ lára rẹ̀?”
-