ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Sámúẹ́lì 21:1-6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Nígbà tó yá, Dáfídì wá sọ́dọ̀ àlùfáà Áhímélékì ní Nóbù.+ Jìnnìjìnnì bá Áhímélékì nígbà tó pàdé Dáfídì, ó sì sọ fún un pé: “Kí ló dé tí o fi dá wá, tí kò sẹ́ni tó tẹ̀ lé ọ?”+ 2 Dáfídì dá àlùfáà Áhímélékì lóhùn pé: “Ọba ní kí n ṣe ohun kan, àmọ́ ó sọ pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan mọ ohunkóhun nípa iṣẹ́ tí mo rán ọ àti àṣẹ tí mo pa fún ọ.’ Torí náà, mo bá àwọn ọ̀dọ́kùnrin mi ṣe àdéhùn pé ká pàdé níbì kan. 3 Ní báyìí, tí búrẹ́dì márùn-ún bá wà ní ìkáwọ́ rẹ, ṣáà fún mi tàbí ohunkóhun tó bá wà.” 4 Àmọ́ àlùfáà náà dá Dáfídì lóhùn pé: “Kò sí búrẹ́dì lásán, búrẹ́dì mímọ́+ ló wà, tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà kò bá ti fọwọ́ kan obìnrin.”*+ 5 Dáfídì dá àlùfáà náà lóhùn pé: “A ti rí i dájú pé a yẹra fún àwọn obìnrin bí a ti máa ń ṣe nígbà tí mo bá jáde ogun.+ Tí ara àwọn ọkùnrin náà bá wà ní mímọ́ nígbà tó jẹ́ pé iṣẹ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì ni wọ́n bá lọ, ṣé wọn ò ní wà ní mímọ́ nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣiṣẹ́ pàtàkì bíi tòní yìí?” 6 Àlùfáà náà bá fún un ní búrẹ́dì mímọ́,+ torí pé kò sí búrẹ́dì míì nílẹ̀ àfi búrẹ́dì àfihàn, tí a mú kúrò níwájú Jèhófà kí a lè fi búrẹ́dì tuntun rọ́pò rẹ̀ ní ọjọ́ tí a mú un kúrò.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́