2 Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Sọ fún Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ pé kó má kàn wá sínú ibi mímọ́+ tó wà lẹ́yìn aṣọ ìdábùú+ nígbàkigbà, níwájú ìbòrí Àpótí, kó má bàa kú,+ torí màá fara hàn nínú ìkùukùu*+ lórí ìbòrí+ náà.
7 Ojúṣe ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ni láti máa ṣe iṣẹ́ àlùfáà tó jẹ mọ́ pẹpẹ àtàwọn ohun tó wà lẹ́yìn aṣọ ìdábùú,+ ẹ̀yin ni kí ẹ máa ṣe iṣẹ́ yìí.+ Mo ti fi iṣẹ́ àlùfáà ṣe ẹ̀bùn fún yín, ṣe ni kí ẹ pa+ ẹnikẹ́ni tí kò lẹ́tọ̀ọ́* sí i tó bá sún mọ́ tòsí.”