36 Kí o fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa tí wọ́n hun pọ̀ ṣe aṣọ* tí ẹ máa ta sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà.+
2 “Mú Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀+ pẹ̀lú àwọn aṣọ,+ òróró àfiyanni,+ akọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àgbò méjì àti apẹ̀rẹ̀ búrẹ́dì aláìwú,+3 kí o sì mú kí gbogbo àpéjọ náà kóra jọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.”