-
Diutarónómì 9:18, 19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Mo wá wólẹ̀ níwájú Jèhófà, bíi ti àkọ́kọ́, fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru. Mi ò jẹ, mi ò sì mu,+ torí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ dá bí ẹ ṣe ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, tí ẹ sì ń múnú bí i. 19 Bí Jèhófà ṣe bínú sí yín gidigidi bà mí lẹ́rù gan-an,+ torí ó ṣe tán láti pa yín run. Àmọ́, Jèhófà tún fetí sí mi nígbà yẹn.+
-