-
Nọ́ńbà 14:13, 14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Àmọ́ Mósè sọ fún Jèhófà pé: “Àwọn ọmọ Íjíbítì tí o fi agbára rẹ mú àwọn èèyàn yìí kúrò láàárín wọn á gbọ́,+ 14 wọ́n á sì sọ fún àwọn tó ń gbé ilẹ̀ yìí. Àwọn náà ti gbọ́ pé ìwọ Jèhófà wà pẹ̀lú àwọn èèyàn+ yìí, o sì ti fara hàn wọ́n lójúkojú.+ Ìwọ ni Jèhófà, ìkùukùu rẹ sì wà lórí wọn, ò ń lọ níwájú wọn nínú ọwọ̀n ìkùukùu* ní ọ̀sán àti nínú ọwọ̀n iná* ní òru.+
-